ADÉLABÚ PE ÀWỌN Ọ̀DỌ́ NÀÍJÍRÍÀ NÍJÀ LÓRÍ ÌDÀGBÀSÓKÈ ÌLÚ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 17, 2019

ADÉLABÚ PE ÀWỌN Ọ̀DỌ́ NÀÍJÍRÍÀ NÍJÀ LÓRÍ ÌDÀGBÀSÓKÈ ÌLÚAdíje pò gómìnà lábẹ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Báyọ̀ Adélabú ti pe àwọn ọ̀dọ́ lórílẹ̀ èdè yìí íjíríà láti jí gìrì sí ojúse wọn gẹ́gẹ́ bi ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ ìdàgbàsókè ìlú pàápàá lọrílẹ̀ èdè Nàíjíríà.

Adélabú, ẹni tí ó jé ọ̀kan nínú àwọn to sọ̀rọ̀ níbi ètò ìfinimọ̀nà kan tó wáyé nílùú Ìbàdàn láìpẹ́ yìí, ṣàpèjúwe àwọn ọ̀dọ́ gẹ́gẹ́ bi òpó tó di awùjọ mú tí wọn kò sì ṣeé fọwọ́ rọ́ tì sẹ́yìn nínú iṣẹ́ ìdàgbàsókè awùjọ.

Ó ní ipa ribiribi ni àwọn ọ̀dọ́ ń kó nínú ìṣàtúntò ìlú àti ní gbogbo ẹ̀ka tó so awùjọ ró pàápàá ètò òṣèlú àti iṣèjọba, nítorí náà ni ó fi yẹ kí wọ́n sakítímápa láti rí i dájú pé wọ́n kó ipa wọn láti mú mùdùnmúdùn ètò iṣèjọba àwarawa kálékáko.

Nígbà tó ń rọ àwọn ọ̀dọ́ náà láti yàgò fún ṣíṣe jàǹdùkú nínú òṣèlú pàápàá gẹ́gẹ́ bí ètò idìbò ṣe ń bọ̀ lọ́nà, Adélabú gbà wọ́n lámọ́ràn láti fi ìbò wọn yan ẹni tí ó wù wọ́n tí yóò ró wọn lágbára gẹ́gẹ́ bí ọwọ̀n láwùjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI