GOMINA AMOSUN LOUN TI YA ILANA IDAGBASOKE ALAADỌTA ỌDUN FUN IPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 17, 2019

GOMINA AMOSUN LOUN TI YA ILANA IDAGBASOKE ALAADỌTA ỌDUN FUN IPINLẸ OGUN

Gomina Ibikunle Amosun tipinlẹ Ogun ti kede sita gbangba pe oun ti ya eto ati ilana idagbasoke alaadọta ọdun silẹ fun ipinlẹ naa, nitori naa, ki wọn ma ṣe gba awọn oloṣelu ẹlẹtanjẹ laaye lati rọwọ mu ninu eto idibo to n bọ lọna yi.

Ana tii ṣe Ọjọru Wẹside ni Gomina Amosun sọrọ yi nibi ipolongo idibo sẹnetọ to n lọ fun, eyi to ṣe lo sawọn agbegbe bii Ita-Baalẹ si Adigbẹ, Ọba, Onidundun, Mọkọlọki ati Mowe, eyi to wa nijọba ibilẹ Ọbafẹmi-Owode nipinlẹ naa. Nibẹ naa ni Gomina Amosun ti tun ti lo anfaani asiko naa polongo ibo fun Aarẹ Muhammadu Buhari.

O ni bo tilẹ jẹ pe ko si ijọba ti yoo pari gbogbo iṣẹ ipinlẹ lẹẹkan ṣoṣo, idi ni yii toun fi ya eto ati ilana naa silẹ fawọn ijọba ti yoo de lẹyin toun ba kuro lori ipo.
Bakan naa lo rọ awọn araalu lati tete jade lọọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn ki asiko to o lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI