ASIRI AAFA TO N FIPA BAWON OMO ILE KEU SUN L'EKO TU O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 3, 2019

ASIRI AAFA TO N FIPA BAWON OMO ILE KEU SUN L'EKO TU O


A fi ki Olorun maa so awon omo kekeeke wa bayii latari bawon agbaaya oloju-komu-o-lo ti won n foruko Olorun boju fi sise ibi, ti won n bawon omolomo laye je kaakiri.

Lojo Fraide ose to koja yi lasiri Aafa kan ti won lo n ko awon omo kekeeke ni Keu, iyen eko Kuraani, Abdulsalam Salaudeen, eni ti won lo n gbe ni ojule kerindinlogun, adugbo Awoyemi, loju ona to lo si Igando, iyen ni Ikotun, ipinle Eko tu si okan lara awon araadugbo naa lowo.

Ibi ti won ni Abdulsalam ti n ba okan lara awon omo to n ko ni Keu e, tiyen ko ju omodun marun un sun karakara leni naa ti ka a, eni naa la gbo pe o fi foonu ya fonran e.

Eni naa ti won foruko bo lasiiri lo mu fonran naa lo fawon olopaa, iyen ni oluleese won l'Eko lati wo o. Lesekese t'asiri yi ti tu sawon olopaa lowo ni won ti loo gbe e nile e.

AWIKONKO gbo pe se lawon ti Abdulsalam jo n gbele koko n gba eri e je nigba tawon olopaa de pe ko le se be e, won kan fe e ba a loruko je lasan ni, paapaa nigba toun naa n so pe iro ni won pa moun.

Nigba ti won mu Abdulsalam de tesan olopaa naa, ni won fi fonran naa han an, bo si se ri ara e ninu fonran yi lo ba bere sii sunkun pe ki won b'oun lasiri.

Komisana olopaa ipinle Eko, Edga Imohimi ti pase pe kise iwadii tubo tesiwaju lati mo awon to tun ti se iru e fun, ki won si le mo iru esun ti won yoo fi kan an nile ejo.

Edga wa a rawo ebe sawon araalu pe ki won ma se gbekele enikeni nipa fifi omo so won, bee lo tun gbawon eeyan lamonran pe bi won ba kofiri awon to n huwa ibaje bi iru eyi ladugbo won, ki won tete fi to awon olopaa leti lati gbe igbese to to labe ofin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI