GOMINA AMOSUN NILO ITOJU ATI ADURA GIDIGIDI - EGBE OSELU APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, January 2, 2019

GOMINA AMOSUN NILO ITOJU ATI ADURA GIDIGIDI - EGBE OSELU APC

...ọrọ ẹ kii ṣoju lasan - Ọladunjoye


Ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun ti ni a fi k'awọn araalu bẹrẹ sii gbadura fun gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun nitori pe ọrọ ẹ kii ṣoju lasan mọ, o si nilo itọju gidigidi nitori pe ẹru ijọba to fẹ ẹ gbe silẹ lọdun 2019 lo n ba a.

Ninu atẹjade ti alukoro ẹgbẹ oṣelu naa, Kọmureedi Tunde Ọladunjoye fi sita lonii, ọjọ keji oṣu kinni in lo ti sọ pe kii ṣe pe awọn deede sọrọ sita, ṣugbọn nigba t'awọn eeyan n beere esi lo jẹ k'awọn sọrọ.

Bẹ o ba gbagbe, lai pe yi ni Gomina Amosun sọrọ n'ita gbangba pe adije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Ọmọba Dapọ Abiọdun ko nii wọle lodun 2019, ṣe lo kan n da ara ẹ laamu, ati pe ẹni toun fa kalẹ, iyẹn Ọnọrebu Adekunle Akinlade lo maa wọle.

Ọrọ naa ti da oriṣiriṣi awuyewuye silẹ, to si n jẹ kayeefi f'awọn kan, paapaa awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa pẹlu bo ṣe jẹ pe inu ẹgbẹ kan naa ni wọn jọ wa.

Kọmureedi Tunde Ọladunjoye sọ pe aarun to maa n ṣe awọn gomina ti wọn ba ti fẹ ẹ kuro lori ipo lo n ṣe gomina Amosun, to si nilo itọju ati adura gidigidi.

O sọ pe awọn ko raaye lati da gomina Amosun lohun ọrọ to sọ naa, dipo bẹẹ, a fi k'awọn rawọ ẹbẹ s'awọn araalu ki wọn foju aanu wo o, ki wọn si maa gbadura fun, nitori pe ẹru nnkan ti yoo ṣẹlẹ lẹyin to ba gbe ipo silẹ lo n ba a.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI