Akọwe fidihẹ fẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun, Ọnarebu Tunde Ọladunjoje ti
pariwo sita fawọn ọmọ Naijira pe ki wọn gba oun lọwọ gomina ipinlẹ naa, Ibikunle
Amosun, nitori pe ṣe lo n fojoojumọ lepa ẹmi oun.
Ninu atẹjade ti ọkunrin naa fi sita nirọlẹ laipẹ yii lo ti sọ pe aṣiri bi
wọn ṣe ni Gomina Amosun da awọn kan sita lati maa ṣọ awọn olori ẹgbẹ oṣelu APC,
paapaa julọ oun, lati se wọn nijamba lo ti tu sawọn lọwọ, idi ni yii tawọn fi
tete pariwo sita.
Ọladunjoye fidi ọrọ naa mulẹ pe ẹnikan lo pe oun lori foonu, to si tu aṣiri
naa, o ni bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe igba akọkọ ree tawọn ti n gba iru ipe bẹẹ,
ṣugbọn eyi to jẹ pabambari ẹ ni wọn lawọn kan to n gbimọ pọ lati gba emi oun lo
ti n wa ọna bi wọn yoo ṣe ri oun pa ki ọjọ Sande to o de, idi ni yii toun fi
tete ke gbajare sita.
O tun sọ pe latilẹ toun ti jẹ gẹgẹ bi ajafẹtọ nileewe titi toun fi di
oloṣelu, oun ko bawọn fa ijangbọn tabi da wahala silẹ ri, bẹẹ loun yoo tẹsiwaju
lati maa ja fẹtọ awọn eeyan lawujọ lai bẹru tabi ṣojo rara.
O wa pari ọrọ ẹ pe fun gbogbo awọn ti wọn n gbinyanju lati ṣe wọn nijanba tabi gbẹmi wọn pe, ẹmi awọn ti kọja bi wọn ṣe ro o.
O wa pari ọrọ ẹ pe fun gbogbo awọn ti wọn n gbinyanju lati ṣe wọn nijanba tabi gbẹmi wọn pe, ẹmi awọn ti kọja bi wọn ṣe ro o.
O ni ki gbogbo agbaye mọ pe bi nnkan tabi ijamba
ba fi le ṣẹlẹ si awọn
agba ẹgbẹ APC, Amosun ni ki wọn beeere lọwọ
ẹ.
No comments:
Post a Comment