Ẹ WÁ GBỌ́ OHUN TÍ ÌYÀWÓ ATIKU SỌ O: Ó NÍ ỌLỌ́RUN Ò NÍ JẸ́ KÍ APC JÁWÉ OLÚBORÍ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 24, 2019

Ẹ WÁ GBỌ́ OHUN TÍ ÌYÀWÓ ATIKU SỌ O: Ó NÍ ỌLỌ́RUN Ò NÍ JẸ́ KÍ APC JÁWÉ OLÚBORÍ

Titi Abubakar


Òkò ọ̀rọ̀ bí èpè bí àdúrà pé Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí ẹgbẹ́ oṣẹ̀lú All Progressives Congress (APC) jáwé olúborí nínú ìdìbò àpapọ̀ tó ń bọ̀ ni Arabìnrin Títí Abubakar, ẹni tíi ṣe ìyàwó olùdíje sípò Àarẹ lórílẹ̀-èdè yìí lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democractic Party (PDP) sọ síta lọ́jọ́rú àná.

Títí Abubakar ló sọ èyí ní Ìpínlẹ̀ Ondo níbi ìpolongo kan níbi tí òun gan-an ti ń pe àwọn obìnrin láti dìbò fún ọkọ rẹ̀, Atiku Abubakar nínú ìdìbò Àarẹ lóṣù tó ń bọ̀.

Ó ṣàlàyé pé ìjọba Àarẹ Muhammadu Buhari ti já orílẹ̀-èdè yìí kulẹ̀ tí ó sì ń wá gbogbo ọ̀nà láti borí nínú ìdìbò náà pẹ̀lú ìpè pé kí wọ́n fi ibò wọn já ẹgbẹ́ òṣèlú APC náà kulẹ̀.

Ó ní gbogbo ìlérí tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣe ni kò wá sí ìmúṣẹ tí ó sì ti bí ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ wàhálà sí àárin ìlú lẹ́yìí tí wọn kò wá àtúnṣe sí.

Aya Abubakar fi kun un pé pẹ̀lú bí wọ́n ṣe kùnà láti mú orílẹ̀-èdè yìí dé ìbùté ògo, wọn sì ń wá gbogbo ọ̀nà láti padà sípò iṣejọba nítorí náà ni ó ṣe yẹ kí àwọn ọmọ Nàíjíríà fi ìbò wọn gbá wọn sí síta.

Ó wá rọ àwọn ìyálọ́jà àti àwọn ọ̀dọ́ ìpínlẹ̀ náà láti yẹra nínú títa káàdì ìdìbò wọn pé àwọn ọmọ égbẹ́ òṣèlú APC kan ń lọ káàkiri láti rà á lọ́wọ́ wọn.   

Títí Abubakar kò sàìrán àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ náà létí láti di ìbò wọn fún ọkọ òun, Atiku Abubakar pẹ̀lú lààyé pé olóòtọ́ ènìyàn ni tí ó ní ètò rẹrẹ fún orílẹ̀ èdè yìí.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI