Ẹ JỌ̀WỌ́, Ẹ FÚN MIKEL LÁYÈ DÍẸ̀ SÍI LÁTI PADÀ SÍ IKỌ̀ SUPER EAGLES - SIASIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 24, 2019

Ẹ JỌ̀WỌ́, Ẹ FÚN MIKEL LÁYÈ DÍẸ̀ SÍI LÁTI PADÀ SÍ IKỌ̀ SUPER EAGLES - SIASIA
Ẹni tí ó ti fìgbà kan rí jẹ́ akọ́nimọ̀ọ́gbá fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù àgbà ilẹ̀ wa, Samson Siasia fẹ́ kí àwọn olólùfẹ́ ikọ̀ náà ṣe sùúrù fún ògbóǹtarigi agbáàáringbùgùn nínú ikọ̀ náà, John Mikel Obi láti ipadà sínú ikọ̀ náà.

Àwọn ọmọ Nàíjíríà pàápàá àwọn olólùfẹ́ agbábọ́ọ̀lù ti ikọ̀ Chelsea tẹ́lẹ̀rí náà ni wọn ti ń pè fún ìpadà rẹ̀ sínú ikọ̀ Super Eagles fún ìdíje ifẹ ẹ̀yẹ ilẹ̀ Afíríkà, AFCON 2019.

Siasia wòye pé ó yé kí wọ́n fún ọdọ́mọdún ọkànlélọ́gbọ̀n náà ní àyè díẹ̀ síi láti yanjú gbogbo isòro tó ń kojú pẹ̀lú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tí ó fẹ́ darapọ̀ mọ́ kí ó to padà wá sínú ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù àgbà ilẹ̀ wa náà.

Lọ́wọ́lọ́wọ́, Mikel kò ní ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù kan ní pàtó lẹ́yìn tí ó ti kúrò ní Tianjin Teda ti lórílẹ̀-èdè China tí ó sì ń gbèrò láti darapọ̀ wá sí ilẹ̀ Yúròòpù kí ó darapọ̀ mọ́ Middlesbrough gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ.

Siasia, ẹni tó ṣàpèjúwe Mikel gẹ́gẹ́ bíi olùfẹ́ ìlú àti balogun rere fún ikọ̀ Super Eagles, ṣàlàyé pé agbábọ́ọ̀lù náà kò ní ṣe ohun tí yóò kéré rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi balogun ikọ̀ náà.

Ó wá fi dá wọn lójú pé Mikel yóò padà sínú ikọ̀ náà lẹ́yìn tí ó bá parí ìdarapọ̀mọ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù mìíràn èyí ti kò ní pẹ́ púpọ̀ mọ́.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI