A Ò NÍ GBÀ KÍ OLÓṢÈLÚ KANKAN LÒ WÁ FÚN JÀGÍDÍJÀGAN – ACOMORAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 24, 2019

A Ò NÍ GBÀ KÍ OLÓṢÈLÚ KANKAN LÒ WÁ FÚN JÀGÍDÍJÀGAN – ACOMORAN


Ẹgbẹ́ àwọn ọlọ́kadà àti oníkẹ̀kẹ́ máwúwá ilẹ̀ wa, ACOMORAN ti sọ́ ọ di mímọ̀ pé òun kò ní gba ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ kankan láàyè láti jẹ́ irinṣẹ́ jàgídíjàgan fún olóṣẹ̀lú kankan nínú ètò ìdìbò tó ń bọ̀.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ́ròyìn sọ̀rọ̀ ní olúùlú ilẹ̀ wa, Abuja, Àkọ̀wé Ìgbìmọ̀ tẹ̀ẹ́kótó ẹgbẹ́ náà, Ado Ibrahim sọ pé égbẹ́ náà ti dá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ lórí pàtàkì yíyéra fún iwà ipá àti jàǹkùdú nínú ìdìbò àpapọ̀ ọdún 2019.

Ó ní ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà, èyí tí yóò máa tẹ̀síwájú títí di ẹ̀yìn ìdìbò káàkiri orílẹ̀-èdè wa, Nàíjíríà, ni àwọn gbé kalẹ̀ láti rí i dájú pé ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí olóṣèlú kan kò lo ọmọ ẹgbẹ́ wọn fún idàlúrú, jíjí apòtí ìbò gbé, rírà àti títa ìbò àti àwọn iwà ipá mìrán tí ó lè sọ ẹgbẹ́ náà lórúkọ burúkú.

Ibrahim fi kún un pé ẹgbẹ́ náà wà gbọingbọin lẹ́yìn Àarẹ Muhammadu Buhari pẹ̀lú àfikún pé àwọn yóò rí i dájú pé ìbò tó tó mílíọ̀nù méjìlá ni àwọn dì fún un.

Ó sọ èyí nígbà tí ó ń yan ìgbìmọ̀ adelé fún ẹgbẹ́ náà, èyí tí yóò ṣètò ìdìbò fún àwọn olóyè tuntun ti ẹgbẹ́ náà tí ó sì ṣàlàyé pé ẹgbẹ́ náà ní ìgbàgbò ńlá nínú iṣàkoso Àarẹ Buhari ju ti ẹlòmíràn lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI