EBOLA PA SÓJÀ MẸ́JÌ NÍ CONGO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 31, 2019

EBOLA PA SÓJÀ MẸ́JÌ NÍ CONGO

Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Congo mẹ́jì kan ni àìsàn Ebola ti rán lọ sọ́run ọ̀sán gangan lọ́jọ’Bọ̀ àná.

Gẹ́gẹ́ bí abẹnugan fún Ikọ̀ Ológun tí ibùba wọn wà ní Beni, Mak Hazukay ṣe sọ, mẹ́ta mìíraǹ nínú àwọn ọmọ ogun náà ni wọ́n ti gbé lọ fún àyẹ̀wò ní iléeṣẹ́ ètò ìlera tó wà ní Beni, Congo.

O fi kún un pé ìgbésẹ̀ tó gbópọn ni àwọn ti gbé láti tọwọ́ àjàkálẹ̀ àìsàn náà bọlẹ̀ láàárín àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ náà.

Láti ọjọ́ kìnní oṣù kẹjọ, ọdún 2018 tí wọ́n ti kẹ́ẹ́fín àìsàn náà ní agbègbè Beni ni ó ti tàn kálẹ̀ dé gbogbo àwọn àgbègbè tó súnmọ́ ọn, tí ó sì ti pa ènìyàn tó dín díẹ̀ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ṣùgbọ́n tí àwọn tí iye wọn dín díẹ̀ ní ọ̀ọ́dúnrún ti gba ìwòsàn tí wọ́n sì ti yẹ̀.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI