GBAJÚMỌ̀ OLÓRIN Ẹ̀MÍ NNÌ, FÚNMI ÀRÁGBAYÉ PÀDÁNÙ ỌKỌ Ẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 31, 2019

GBAJÚMỌ̀ OLÓRIN Ẹ̀MÍ NNÌ, FÚNMI ÀRÁGBAYÉ PÀDÁNÙ ỌKỌ Ẹ̀

Àná òdé yìí ni, Alàgbà Bọ́lá Àrágbayé tí i ṣe ọkọ òǹkọrin àti Àarẹ̀ Ẹgbẹ́ Àwọn Òǹkọrin Ẹ̀sìn Kìrìstẹ́nì nílẹ̀ Nàíjíríà, Fúnmi Àrágbayé kí ayé pé ó dìgbọ́ṣe.


Alàgbà Àrágbayé ló re ibi ìsinmi ní dédé aago méjì àbọ̀ ọ̀sán àná, Ọjọ́rú lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlọgọ́rin nílé ìwòsàn ìkọ́ni, UCH ní Ìbàdàn.

Nígbà ayé rẹ̀, Alàgbà Àrágbayé ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi akọ̀ròyìn ìwé-ìròyìn Nigeria Tribune lábẹ́ gómìnà àná, Lateef Jaknade, kí ó tó darapọ̀ mọ́ ìwé-ìròyìn Sketch lọ́dún 1967 níbi tí ó ti di Olóòtú Ìròyìn Àgbà.

Ọdún 1981 ni wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bíi akọ̀wé àgbà fún ètò ìròyìn lábẹ́ Olóògbé Adékúnlé Ajásin, ẹni tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ gómìnà Ìpínlẹ̀ Ondo.

Alàgbà Bọ́lá Àrágbayé pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gọrin ní ọjọ́ kẹ̀wàá oṣù kọ̀kànlá, ọdun 2018, ó sì fi ìyàwó, ọmọ, ọmọọmọ àti àwọn mọ̀lẹ́bí sílẹ̀ sáyé lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI