ẸGBẸ OṢELU APC NI MO WA, EMI KO SI NINU AWỌN KỌMISANA TO K'ỌWE FIPO SILẸ - BAṢỌRUN ỌLADIPỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, January 16, 2019

ẸGBẸ OṢELU APC NI MO WA, EMI KO SI NINU AWỌN KỌMISANA TO K'ỌWE FIPO SILẸ - BAṢỌRUN ỌLADIPỌ

Komisana fọrọ aṣa ati irin ajo igbafẹ nipinlẹ Ogun, Baṣọrun Muyiwa Ọladipọ ti sọ pe oun ko si ninu awọn kọmisana to le k'ọwe fipo sipo sile latari ọrọ oṣelu to n lọ lọwọ nipinlẹ naa, ati pe inu ẹgbẹ oṣelu APC to fi ipo Kọmisana da oun lọla loun si wa, ti ko si nnkan to le gbe oun kuro nibẹ. Baṣọrun Ọladipọ sọrọ yi lasiko to n ba akọroyin AWIKONKO sọrọ ninu ọfiisi e to wa ni Oke-Mọsan niluu Abẹokuta lọjọ Tuside ana. Bẹẹ lo tun so awọn aṣeyọri ẹ gẹgẹ bii Kọmisana. Ẹ ka ifọrọwerọ naa bo ṣe lọ: 

Baṣọrun Ọladipọ
AWIKONKO: Ipo wo ni ileeṣẹ eto aṣa ati igbafẹ wa lọwọlọwọ?
BAṢỌRUN: Ẹ ṣeun, ileeṣẹ eto aṣa ati igbafẹ ti mo jẹ oludari ẹ nipinlẹ Ogun lonii, o jẹ ileeṣẹ ti Amofin Ibikunle Amosun n dari ẹ, o tun jẹ ọkan lara awọn ileeṣẹ to da silẹ nigba ti Gomina Amosun de ijọba lati gbe aṣa wa larugẹ ati lati jẹ kawọn eeyan mọ nipa eto igbafẹ kaakiri Naijiria ati kaakiri agbaye. Gbogbo ẹ julọ lagbara Ọlọrun, a n gbiyanju agbara wa lati rii pe a ṣe ju eyi ti a ba nilẹ lọ, mo si mọ pe Ọlọrun n gbakoso.

AWIKONKO: Bawo ni imurasilẹ ayẹyẹ ọdun ilu ilẹ Afrika t’ọdun yi, paapaa bi ijoọba yi ṣe n ko igba wọle?
BAṢỌRUN: O ti le ni ọdun kẹta ti a ti bẹrẹ, ayẹyẹ ọdun kẹrin la fẹ ẹ ṣe lọdun yi, ẹ ma si gbagbe pe gbogbo ọsẹ kẹta ninu oṣu kẹrin ọdọọdun la maa n ṣe e. Mo fẹ ẹ dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ayẹyẹ naa ti gbẹrẹgẹjigẹ, o ti muna d’oko daadaa, to jẹ pe gbogbo agbaye ti tẹwọ gba a, gbogbo agbaye ni wọn n fẹ ẹ wa lati darapọ mọ wa. A ti bẹrẹ ipa kiko nipa ayẹyẹ t’ọdun yi, ti mo si fi n da a yin loju pe o maa larinrin ju eyi to kọja lọ. Ti ẹ mo ipinlẹ Ogun, ẹ maa rii pe ipinlẹ to dangajia nipa aṣa ni, awa si la maa n ṣe ipo kinni-in ninu gbogbo nnkan, a si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ko doju iṣẹ wa bo’lẹ, ko si tun d’oju adura ti wa, a ti bẹrẹ imurasilẹ, ṣugbọn o digba ti asiko ba n sunmọ etile ka too le fi awọn nnkan ti a ni sita.


AWIKONKO: Ipinlẹ Ogun lo maa n saba ṣe ipo kinni-in nibi eto ti wọn ba ti lọọ figagbaga, kini lawọn aṣiri aṣeyọri yii?
BAṢỌRUN: Ko si aṣiri kankan nidi ẹ bi ko ṣe pe nnkan ti a mọn ọn ṣe niyẹn, nitori pe wọn maa n sọ pe ‘abinibi yatọ si abiliti’, wọn bi wa mọ aṣa nipinle Ogun ni, ẹni to n dari aṣa ni ilẹ kaarọ-o-jiire-bi, tabi ki n sọ pe bi ẹ ba maa darukọ awọn to ti dari ọrọ aṣa sẹyin nilẹ Yoruba, ko si bi ẹ ṣe maa darukọ, ti ẹ ko nii darukọ Hubert Ogunde, nigba ti awọn baba wa yi ti fi apẹẹrẹ rere le’lẹ fun wa, ki lo wa a de ti a ko nii ṣe ju ti wọn lọ?

AWIKONKO: Gomina ṣeleri lati mọ ere ti yoo jọ Baba Ogunde lọdun to kọja, ṣugbon a ko tii ri apẹẹrẹ ileri naa, ki lo fa a?
BAṢỌRUN: Gomina ti ri bi ọrọ ayẹyẹ ọdun ilu yẹn ṣe n lọ pe o ti n kọja ipinlẹ Ogun nikan nitori pe gbogbo gbaye ni wọn tẹwọ gba a, ti wọn si n fẹ ẹ wa. A jọ ma maa ṣe e ni, ko si ẹni ti gbọn tan, ti ẹ ba si ayẹyẹ t’ọdun yi, bi ẹ ba ri awọn ibi ti a ku si, ti ẹ si fi to wa leti, a maa ṣe ayipada. Ju gbogbo ẹ lọ, nnkan ti mo fẹ ki ẹ mọ daju ni pe ọdun ilu ti de, o si ti duro sipinlẹ Ogun lati gbe aṣa wa larugẹ ati lati sọ ọ di ibi igbafẹ.


AWIKONKO: Ọdun kẹrin yin lo fẹ ẹ kogba wọle yi, ki lawọn nnkan aritọka si yin gẹgẹ bi aṣeyọri yin?
BAṢỌRUN: Aṣyọri pọ loriṣiriṣi, paapaa latigba ta a ti de ori oye yi, gbogbo awọn ti wọn ba wa fun iranlọwọ lati ṣagbatẹru wọn la maa n gbaruku ti, ti wọn si maa n wo wa gẹgẹ bi awokọṣe, ẹwa ni aṣa, aṣa ni ẹwa, ẹbun l’obinrin, a tun n ṣe omidan obinrin to je ti aṣa

AWIKONKO: Kọmisana fun ọrọ oyi jijẹ ati ijọba ibilẹ lẹ jẹ ni saa akọkọ ijọba Gomina Amosun, ṣugbọn ti aṣa ati irin ajo igbafẹ lẹ jẹ bayii, ipo wo ninu mejeeji lẹ gbadun ju?
BAṢỌRUN: Mejeeji lo dara, ikan wa fawọn lọba-lọba ati ijọba ibilẹ, ekeji jẹ ti aṣa ati ọrọ igbafẹ, ti a ba si n sọrọ nipa aṣa, awọn lọba-lọba ni wọn muu dani l’agbegbe won, ijọba ibilẹ ni agbegbe ti mo n sọ yi wa, fun idi eyii, mejeeji lo wọnu ara wọn, mi o le sọ pe eyi lo dara, mi o si le sọ pe eyi ni ko dara, ọkan kan gbe pẹẹli ju ọkan lọ ni nitori pe, owo wa ninu ọkan, iyi lo wa ninu ekeji, iyi ati owo bi ẹ ba wo o, wọn jọ n rin ni. Yoruba si maa n sọ pe bi ẹ ba n wa owo lọ, ti ẹ wa a pade iyi lọna, afi ki ẹ pada sile nitori pe bi a ba ri owo naa tan, iyi la maa fi ra. Mejeeji lo ni owo ninu, mejeeji naa lo ni yii, wọn kan pọ ju ara wọn lọ ni.

AWIKONKO: Ki lamọnran yin fawọn ọmọ ilẹ adulawọ nipa aṣọ ibilẹ wiwọ?
BAṢỌRUN: Amọnran mi ni pe ki wọn dakun-dabọ, lootọ ọtọ ni ẹsin, ọtọ si ni aṣa, ati pe lootọ ni pe aṣa oyinbo ti wọle tọ wa wa, ṣugbọn sibẹ, a ko gbọdọ ki aṣa wa parẹ, aṣọ wiwọ jẹ pataki nnkan to n gbe aṣa larugẹ, ki awọn ẹlẹsin mejeeji to o de silẹ wa, o ni ẹsin ti a n sin-in, ko si si ẹsin kankan ninu mẹtẹẹta to maa sọ pe ki ẹ wa ta ẹjẹ eeyan silẹ, Ọlọrun kan-naa-an ni gbogbo wa n sin-in, ẹsin lo kan yatọ. Mo wa n gba gbogbo wa lamọnran pe bi a ko ba le maa wọ aṣọ ibilẹ wa lojoojumọ, ẹ maa wọ ọ lẹẹmeji laarin ọsẹ, awọn pasitọ wa ti wọn n sọpe afi kawọ wọ suutu (suit) kawọn to o le waasu lori pẹpẹ ko ṣe aṣa wa daadaa, wọn ko jẹ apẹẹrẹ rere fawọn ọmọlẹyin wọn nipa gbigbe aṣa wa larugẹ, bẹẹ na lawọn musulumi, bo tilẹ jẹ pe awọn si maa n we lawaani, ju gbogbo ẹ lọ, afi ka ṣe e gẹgẹ bi wọn ti n ṣe e, ko le ba a rii bo ti n ri.

AWIKONKO: Asiko oṣelu la wa yi, ninu ẹgbẹ wo lẹ n ṣe ninu ẹgbẹ oṣelu APC ati APM?
BAṢỌRUN: Looto awuyewuye ti n waye lori ẹ, tawọn eeyan si n fẹ ẹ mọ ibi ti mo wa ninu ẹgbẹ oṣelu mejeeji yi, ṣugbọn mo n fi asiko yi sọ fun gbogbo awọn eeyan pe ẹgbẹ oṣelu APC, iyẹn All Progressives Congress ni emi Baṣọrun Muyiwa Ọladipọ wa, mi o ni ibi ti mo n lọ. Ẹgbẹ oṣelu APC jẹ ẹgbẹ oṣelu ti baba wa, Oloogbe Ọbafẹmi Awolọwọ bẹrẹ ẹ pẹlu Action Group, to tun pada di ẹgbẹ oṣelu Alliance for Democracy (AD), to tun di ẹgbẹ oṣelu Social Democratic (SDP) nigba kan, tawọn adari tun wa a ko ara wọn jọ lati sọ ọ di APC ti gbogbo wa wa bayii, ko si nii bajẹ.


AWIKONKO: Ipolongo idibo lo n lọ lọwọ yi, ki lo fa a ti ẹ ko fi jade?
BAṢỌRUN: Mo fẹ ẹ jade tẹlẹ fun ipo Gomina ipinlẹ Ogun, ṣugbọn Ọlọrun lo sọ pe asiko ko tii to, mo si mọ pe lagbara Ọlọrun naa, mo ṣi maa dari ipinlẹ Ogun ti Ọlọrun ba sọ pe asiko ti to lati di gomina ipinlẹ Ogun. Ṣugbọn lọwọlọwọ bayii, ẹni ti ẹgbẹ oṣelu wa APC fa silẹ, iyẹn Ọmọba (Dọkita) Dapọ Abiọdun la maa ṣiṣẹ fun, to si maa wọle lagbara Ọlọrun.

AWIKONKO: Ki lo fa a to fi jẹ pe Dapọ Abiọdun lẹ tẹle, ti ẹ ko tẹle ẹni ti Gomina Amosun to yan yi gẹgẹ bi Kọmiṣana fa kalẹ, iyẹn Ọnarebu Adekunle Akinlade?
BAṢỌRUN: Ọga wa ni Gomina Ibikunle Amosun, Ọga mi ni wọn, Gomina mi si ni wọn, awọn naa si ni wọn yan mi sipo. Lọwọlọwọ bayii, ẹgbẹ oṣelu APC ni ọga mi, Gomina Ibikunle Amosun wa, APC yẹn lemi ati ogunlọgọ awọn eeyan naa wa. Yoruba bọ, wọn ni gbogbo wa ko le sun ka kọri sibi kan naa-an, bẹẹ ni wọn tun n sọ pe atori l’aye nitori pe to ba lu siwaju, o maa tun lu s’ẹyin, wọn tun ni aye funra ẹ dabii gangan ni, iwaju to kọ eeyan kan, ẹyin lo kọ si ẹnikeji, o ni nnkan ti ọga mi ri ti wọn fi sọ pe Ọnarebu Akinlade lawọn maa tẹle, o si ni nnkan ti emi naa ri ti mo fi sọ pe Dapọ Abiọdun ni maa tẹle. Oju ọrun to ẹyẹ fo lai fi ara kan ara wọn.

AWIKONKO: Pupọ ninu awọn ẹlẹgbẹ yin gẹgẹ ni Kọmisana ni wọn ti kọwe fipo silẹ, ki lo fa a ti ẹyin si fi suro, niwọn igba ti ẹ ko tẹle ẹni ti Gomina Amosun fẹ ẹ fa kalẹ?
BAṢỌRUN: Ko si nnkan ti mi o fi k’ọwe fipo silẹ, idi ni pe APC lo wa n’ijọba, Gomina Amosun ko sọ pe awọn n lọ si APM, wọn kan sọ pe awọn faramọ adije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APM ni. Lọwọlọwọ bi mo ṣe n ba a yin sọrọ yi, ijọba APC lo wa nipinlẹ Ogun, ibẹ si ni mo wa, to ba wa di ọla, tijọba Amosun ba sọ pe APM lawọn n lọ, ti ẹ si tun ri mi ninu ẹgbẹ oṣelu APC, igba yẹn lẹ le lẹnu ọrọ, ṣugbọn ni bayii, APC ti Gomina Amosun wa, lemi naa wa, igba to ba si wun mi ni mo le sọ pe mo fẹ ẹ kuro.

AWIKONKO: Pẹlu bi ẹ ṣe fi erongba yin han bayii, ṣe ẹ ko le ro o pe Gomina le yọ yin n’ipo?
BAṢỌRUN: To ba ri bẹ ẹ, a jẹ pe bi ọga mi ṣe fẹ ẹ niyẹn, ti a ko ba lọ, a kii de, ẹ jẹ ko ṣi digba yẹn naa.

AWIKONKO: Ọrọ amọnran yin fawọn ọmọ ipinlẹ Ogun, paapaa awọn oludibo?
BAṢỌRUN: Amọnran mi fawọn ọmọ ipinlẹ Ogun, paapaa awon awọn ewe ni pe ki wọn ma ba ara wọn ja. Olori to ba sọ pe ki wọn lo ba oun pa eeyan, ki wọn lọ ba oun gun ẹnikan l’ọbẹ, ẹ sọ fun un pe ko kọkọ fi ọmọ ẹ siwaju, ti ẹ ba sọ bẹẹ, awọn naa a ki ọwọ ọmọ wọn bọ asọ. Adari ti ko ni iye, ti ko bẹru Ọlọrun lo maa ni ki wọn lọ ba oun paayan, ki wọn lọ ba oun da ilu ru. Ki la gbe ta n gbin, ṣugbọn adari to ba ji laarọ, to ba ro ibi si ẹda ẹgbẹ ẹ, yatọ si pe ko dije, ki wọn si tẹka fun un, ki ẹnikan wọle, ki ẹnikeji si ja kulẹ, ko ranti pe oun naa bimọ. Adura ti mo si maa gba lojoojumọ ki n to o jade ni pe ko ri fun eeyan gẹgẹ bi ero ọkan ẹ si mi. Ọlọrun kii ṣe’ka, ma j ka maa ran oniṣẹ iku si ara wa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI