Ko din lẹgbẹrun marun un awọn arugbo tọjọ ori wọn bẹrẹ lati aadọrin (70)
ọdun lọ soke ni Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun fi ounjẹ bọ lati fi saami ayẹyẹ
ọjọ ibi ọdun mọkalelọgọta (61) to ṣe lonii.
Ayẹyẹ to waye ninu gbọngan aṣa, Cultural Centre to wa ni Kuto niluu
Abẹokuta lto waye pẹlu ayẹyẹ ọdun kẹjọ ti ṣise iranlọwọ fawọn arugbo, eyi ti
ileeṣẹ iyawo gomina gbe kalẹ lọdun mẹjọ sẹyin, iyẹn ni gbara ti Gomina Amosun de
ipo.
No comments:
Post a Comment