IPINLẸ OGUN ṢETAN LATI FỌWỌSOWỌPỌ PẸLU INEC – AMOSUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 26, 2019

IPINLẸ OGUN ṢETAN LATI FỌWỌSOWỌPỌ PẸLU INEC – AMOSUN

Gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun ti ṣeleri pe oun pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun ti ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹli ajọ eleto idibo nipinlẹ naa lati rii pe ko nii si iwa jagidijagan, toun gbogbo yoo si lọ nirọwọ-irọsẹ.

Amosun lo sọrọ yi lasiko to n si idanilẹkọ ọlọjọ kan ṣoṣo ti ajọ to n ṣeranlọwọ fawọn ọlọpaa atawọn araalu, iyẹn Police Community Relations Committee, PCRC gbe kalẹ ninu gbọngan ayẹyẹ aṣa, Cultural Center niluu Abeokuta lonii.

Nigba to n gba ẹnu gomina Amosun sọrọ, akọwe ijọba ipinlẹ naa, Taiwo Adeoluwa sọ pe oun mọ pe ajọ naa ti mura silẹ daadaa, toun si mọ pe ẹru yoo ti maa bawọn araalu nipa wipe wahala le ṣẹlẹ, ṣugbọn oun mọ pe awọn ọlọpaa yoo ṣe gbogbo eto to ba yẹ lati ṣe lati rii pẹ alaafia jọba.

Bakan naa nigba to n gbe oriyin fun ajọ PCRC, Gomina Amosun sọ pe inu oun dun bi ajọ naa ṣe n gun agba sii, to si jẹ pe awọn gan an nileeṣẹ to n ṣeranlọwó to pọju fawọn ọlọpaa. O ni nigba ti ajọ naa maa bẹrẹ iṣẹ pẹrẹu, awọn eeyan wọn ko ju ẹgbẹrun meji aabọ lọ, ṣugbọn ni bayii, wọn ti le lẹgbẹrun lọna ọgọrun.


Eto naa ṣi n lọ lọwọ. Ẹkunrẹrẹ n bọ laipẹ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI