LẸYIN ỌSẸ MEJI, AWỌN ỌLỌPAA TU DINO MELAYE SILẸ L'ỌGBA WỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 22, 2019

LẸYIN ỌSẸ MEJI, AWỌN ỌLỌPAA TU DINO MELAYE SILẸ L'ỌGBA WỌN


Ni nnkan bi aago mejila ọsan onii, Tuside ni ileeṣẹ ọlọpaa tu Sẹnetọ Dino Melaye to n ṣoju ẹkun Kogi West nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja silẹ pe ko maa lọ lati lọọ tọju ara ẹ latari bo ṣe sọ pe ara oun ko ya ni gbara ti wọn gbe e.

Bi ẹ ko ba gbagbe, o ti pe ọsẹ meji bayii ti ileeṣẹ ọlọpaa latilu Abuja ti lọọ gbe Sẹneto Melaye nile ẹ to wa ni Kogi, latari awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

Ọkan lara awọn mọlẹbi Dino Melaye lo tu aṣiri naa fawọn oniroyin pe Dino ti wa nile ẹ, nibi to ti n sinmi wahala to ṣe pẹlu awọn ọlọpaa.

Lọjọ Monde ana ni ile ẹjọ giga tiluu Abuja fun Dino Melaye lanfaani pe ki wọn gba beeli e, ṣugbọn tawọn ọlọpaa sọ pe ko si nnkan to jọ ọ, ọdọ awọn ni yoo wa tawọn yoo fi pari iwadii awọn, eyi gan an lo jẹ kawọn ololufẹ ẹ Dino yari kanlẹ pe afi ki wọn tuu silẹ laarin wakati mẹrinlelogun bi wọn ko ba fẹ wahala.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI