Ó GBẸNUTÁN: AGBÁBỌ́Ọ̀LÙ CARDIFF TUNTUN DI ÀWÁTÌ PẸ̀LÚ ỌKỌ ÒFURUFÚ TÓ GBÉ E - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 23, 2019

Ó GBẸNUTÁN: AGBÁBỌ́Ọ̀LÙ CARDIFF TUNTUN DI ÀWÁTÌ PẸ̀LÚ ỌKỌ ÒFURUFÚ TÓ GBÉ E


Emiliano Sala

Títí ìdàgbà tí ẹ fi ń ka ìròyìn yìí ni àwọn aláṣe tó ń rí sí ìgbòkègbódò ọkọ̀ òfurufú ilẹ̀ France fi ń wá Emiliano Sala, agbébọ́ọ̀lù tuntun tí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Cardiff City ṣẹ̀ṣẹ̀ rà pẹ̀lú ọkọ̀ òfurufú tó ń gbé e bọ̀ wá si pápá ìṣeré ti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà.

Àwọn alásẹ tó ń rí sí igbòkègbódò ọkọ̀ òfurufú ilẹ̀ France ṣàlàyé pé ọkọ̀ òfurufú tó gbé Emiliano Sala náà ni ó di àwáti nínú ìrìnàjò rẹ̀ láti France sí Cardiff lẹ́yìn ìsẹ̀jú mẹ́ẹ̀dógún tó gbéra kúrò ní pápákọ̀ òfurufú Nanates ní aago mẹ́jọ kọjá ìṣẹ̀jú mẹ́ẹ̀dógún ìrọ̀lẹ́.

Sala, ọmọ ọdún mẹ́jìdínlọ́gbọ̀n (28) tí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Cardiff rà ní mílíọnù mẹtàdínlógún owó yurò (€ 17million) ní ó wà pẹ̀lú àwọn méjì mìíràn tí ó wà nínú ọkọ̀ òfurufú náà èyí tí ìgbàgbọ́ wà pé ó já sínu òkun ní eré kùsù kan nílẹ̀ France.

Gẹ́gẹ́ bí atẹ̀jáde kan tí àwọn ọlọ́pàá Guernsey nilẹ̀ England fi síta ṣe sọ, àwọn ikọ̀ adóòlà ẹ̀mí láti ilẹ̀ France àti England ti tú jáde láti wá ọkọ̀ òfurufú náà nínú èyí tí wọ́n ti rí orísirísi nǹkan àfọ́kù lójú omi ní agbègbè náà.

Àwọn ọlọ́pàá náà ṣàlayé pé àwọn kò ní dáwọ́ wíwá okọ̀ òfurufú náà bí wọ́n tilẹ̀ kojú ìsorò ojú wàhálà ọjọ́ tí kò dára.

Lọ́wọ́lọ́wọ́, àwárí àwọn nǹkan àfọ́kù yìí ni ó jẹ́ ohun ìjayà fún àwọn olólùfẹ́ Sala pàápàá àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ nínú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nantes pé ó ṣée ṣe kí ọkọ̀ òfurufú náà já sínú òkun.
Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gbé e sí orí ìkànnì Twitter, gbogbo ìgbaradi fún ìfésẹ̀wọnsẹ̀ tí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nantes ní ni wọ́n ti wọ́gi lé pẹ̀lú bí ogunlọ́gọ̀ àwọn agbábọ́ọ̀lù ẹgbẹ́ rẹ̀ àti àwọn alátìlẹ́yìn wọn ní Nantes ṣe tú síta láti ṣe ìdárò rẹ̀.

 Láti ọdún 2016 ni Emiliano Sala ti darapọ̀ mọ́ Nantes tí ó sì ti mi àwọ̀n lẹ́ẹ̀ẹmẹtàlá kí ó tó tọwọ́ bọ̀wé láti darapọ̀ mọ́ Cardiff City.

Bí àwọn ọlapàá bá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lọ́ọ̀ọ́tọ́ ni ọkọ̀ òfurufú náà já sínú òkun, yóò di èkejì tí irúfẹ́ ìṣelẹ̀ yìí yóò wáyé láàárín oṣù mẹ́ta tí ẹni tó ni ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Leicester City, Vichai Srivaddhanaprabha pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sínú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú èyí tó sẹlẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gbéra pẹ̀lú hẹlikọ́pítà rẹ̀ ní pápá ìṣeré ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà nílẹ̀ England.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI