O DAMI LOJU PE MAA DI GOMINA IPINLẸ OGUN LỌDUN 2019 YI - ADUNNI-KASSIM - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 26, 2019

O DAMI LOJU PE MAA DI GOMINA IPINLẸ OGUN LỌDUN 2019 YI - ADUNNI-KASSIM

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta
 
Adije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu United Democratic Party, UDP nipinlẹ Ogun, Dokita Arabinrin Jackie Adunni Kassim ti sọ ọ di mi mọ pe o da oun loju lati di gomina ipinlẹ naa lọdun 2019 ti a wa yi. 

Laipẹ yi ni Arabinrin Adunni Kassim sọrọ naa niluu Abẹokuta lasiko to gba ẹnu alakoso fọrọ iroyin ati bo ṣe n lọ ẹ, Ọgbẹni Fẹmi Oyewẹsọ sọrọ nipa ipinu ẹ lati jade dupo gomina, paapaa bo tun ṣe jẹ obinrin. O sọ pe looto loun jẹ obinrin, ṣugbọn iyẹn ko ni koun ma jawe olubori ninu idibo to n bọ yi.

Oyewẹsọ sọ pe, obinrin naa ni yoo jẹ obinrin akọkọ ninu itan ipinlẹ Ogun lati di gomina, ọdun yi si ni yoo jẹ pẹlu ogo Ọlọrun, ti ko si si nnkan to le yẹ ẹ.

O tun jẹ ko ye wa pe latigba ti wọn ti da ipinlẹ naa silẹ, ko tii si obinrin to dari akoso ipinle naa, to si jẹ pe awọn ọkunrin ti wọn n yan sipo lati sakoso ni wọn ko ṣe awọn nnkan to yẹ lati mu igbe aye irọrun de fawọn araalu.

Jackie Adunni Kassim tun ni bo tilẹ jẹ pe oun ti bẹrẹ ipolongo idibo naa lati ojule si ojule, agbegbe si agbegbe, toun si n bawọn eeyan sọrọ, ti wọn si n fọkan oun balẹ, o daju pe oun yoo jawe olubori

Nigba to n sọ nnkan meje pataki to fẹ ẹ ṣe fawọn ọmọ ipinlẹ naa, Adunni Kassim sọ pe “Eto ilera to peye, irolagbara awọn eeyan, eto ẹkọ to peregede, eto aabo to peye, agbegbe ti yoo mu ilera gidi wọlu, iṣejọba ti kii ṣoju-ṣaaju, titun awọn ibi igbafẹ ati aṣa ṣe, pẹlu awọn min in lo wa nilẹ ti mo fẹẹ ṣe.

“O dami loju pe lọjọ keji oṣe kẹta ọdun yi, emi ni ajọ eleto idibo, iyẹn INEC yoo kede gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori, nitori pe gbogbo awọn araalu ni wọn ti fọkan mi balẹ, ti wọn si rii daju pe emi gan an lẹni to kaju oṣuwọn lati ṣe e.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI