Ẹ MA FI ỌBẸ ẸYIN JẸ MI NIṢU O – KAṢAMU PARIWO FUN AJỌ INEC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 26, 2019

Ẹ MA FI ỌBẸ ẸYIN JẸ MI NIṢU O – KAṢAMU PARIWO FUN AJỌ INEC

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta 
Adije sipo gomina nipinlẹ Ogun labẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Sẹnetọ Buruji Kaṣamu ti pariwo sita fun igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ naa pe ki wọn bọwọ fun aṣẹ tile ẹjọ pa pe oun ni adije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu naa nipinlẹ Ogun, eyi ti ajọ INEC naa si fọwọ sii pẹluu.

Kaṣamu lo sọrọ naa lonii lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ nipinlẹ Eko lati tako ọrọ ti agbẹnusọ fun ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Kola Ọlọgbọdiyan sọ laipẹ yi pe Ọnarebu Ladi Adebutu lawọn mọ gẹgẹ bi adije sipo gomina nipinle Ogun.

Bẹ o ba gbagbe, lọjọ kẹtadinlogun oṣu yi ni ajọ INEC gbe orukọ awọn adije patapata sita fawọn araalu lati mọ, eyi to jẹ pe orukọ Kaṣamu ni wọn gbe sita gẹgẹ bi adije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP, paapaa julọ to tun jẹ pe gbogbo awọn orukọ ti wọn wa labẹ Ọgbẹ Bayọ Dayọ lo tun jade pẹluu.

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe ẹgbẹ oṣelu PDP ti pin si meji tipẹ, bawọn kan ṣe faramọ alaga igun Ọnarebu Sikirulai Ogundele, bẹẹ lawọn kan fara mọ igbimọ ti ọgbẹni Bayọ Dayọ n ṣakoso ẹ.

Eyi to n jẹ kayeefi ni pe Ladi Adebutu lawọn igbimo amuṣẹṣe, iyẹn National Working Committee ẹgbẹ naa fọwọ si, eyi tawọn kan ko faramọ.

Ṣugbọn lọjọ Wẹside ni Ọgbẹni Festus Okoye to jẹ Kọmiṣana fọrọ iroyin ati didawọn eeyan lẹkọọ nipa kaadi idibo fun ajọ INEC sọrọ sita pe Sẹnetọ Buruji Kaṣamu lawọn mọ gẹgẹ bi adije sipo gomina pẹlu aṣẹ kọọtu to wa lọwọ awọn gẹgẹ ojulowo.

Ọjọ Tọside ni Ọlọgbọdiyan sọrọ ti ẹ niluu Abuja pe lọpọ igba lawọn ti sọ fun ajọ INEC pe Adebutu ni ki wọn mu, kii ṣe Kaṣamu, nitori pe awọn ko mọ ọn.

Nigba to n sọrọ, Kaṣamu ni oun ṣi ni adije sipo gomina lẹgbẹ nipinlẹ Ogun pẹlu aṣẹ tile ẹjọ pa lọjọ kẹrinla oṣu yi, ti aṣẹ naa si de ajọ INEC ati ẹgbẹ oṣelu PDP.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI