O MA ṢE O; WỌN LU IYAALE ILE PA SINU IGBO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 31, 2019

O MA ṢE O; WỌN LU IYAALE ILE PA SINU IGBO


Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta

Kayeefi niku iyaale ile kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Glory Omo-Ohwo ti wọn lawọn agbenipa pa danu sinu igbo kan niluu Yenogoa ṣi n jẹ fawọn eeyan latari bi wọn ko tii ṣe mọ awọn to wa nidi ẹ.

Ohun ta a gbọ ni pe Glory, ọmọ bibi ilu Oreba/Uhweru nipinlẹ Delta ti wọn lo n gbe lagbegbe Akenfa Epie nipinlẹ Bayelsa ji ni nnkan bi aago marun, laarọ kutu ọjọ Tusde to kọja yi lati gba ibi to ti n ta ẹja ẹ lọ, nitori ti wọn ni ẹja lo n ta.

Glory ti wọn loo ti bimọ mẹrin naa ni wọn sọ pe, ẹja to ra lọja nla kan to gbajumọ daadaa lo fẹ lọọ yan laarọ ọjọ naa lẹyinkule ile to n gbe. Ibi ti wọn lawọn ọmọ ẹ rii mọ niyẹn.

AWIKONKO gbọ pe bawọn ọmọ ẹ ṣe ji ni wọn lọọ wo o nibi to ti maa n yan ẹja, ṣugbọn to jẹ pe kaka ki wọn rii, bata ẹṣẹ kan lasan ni wọn ri, ti wọn ko si mọ bo ṣe rin in.

Latigba naa la gbọ pe wọn ti n wa Glory ti wọn ni ọkọ ẹ ba iṣẹ aje ti ẹ lọ. Nigba ti wọn maa pada ri oku Glory larọ ọjọ Wẹside ana, oku ẹ ni wọn ba ninu ile akọku kan to wa ldugbo to n gbe, ti wọn ti figi lu ori ẹ fọ, ti wọn si n wo ọpọlọ ẹ nilẹ.

Lara awon araadugbo naa to firoyin yi to wa leti jẹ ko ye wa pe o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn kan ni wọn dọdẹ ẹ wa sibẹ lati fipa ba a sun, ati pe awọn eeyan naa le jẹ ẹni mimọ, idi ni yii ti wọn fi luu pa nigba ti Glory da wọn mọ, kaṣiri si ma baa tu sita.

Wọn ni eeyan jẹjẹ ti kii da si ọrọ ọlọrọ ni Glory jẹ, ati pe kii baayan ja, pẹlu bi wọn ṣe n ma a waja ẹ to. Ẹrin ati awada la gbọ pe Glory maa fi n dawọn eeyan lohun.

Titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan la gbọ pe awọn ọlọpaa ṣi n ṣewadi awọn to wa nidi iku ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI