Ẹ MA JẸ KAWỌN ỌKỌ ATAWỌN ỌMỌ YIN LỌWỌ NINU IWA JAGIDIJAGAN LASIKO OṢELU YI – IYAWO GOMINA IPINLẸ EKITI PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 31, 2019

Ẹ MA JẸ KAWỌN ỌKỌ ATAWỌN ỌMỌ YIN LỌWỌ NINU IWA JAGIDIJAGAN LASIKO OṢELU YI – IYAWO GOMINA IPINLẸ EKITI PARIWO SITA


Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun

Iyawo Gomina ipinlẹ Ekiti, Erelu Bisi Fayẹmi ti ke gbajare sawọn obi ati alagbatọ, paapaa awọn obinrin ti wọn ṣe abiyamọ pe ki wọn ti ọwọ awọn ọkọ atawọn ọmọ wọn bọnu aṣọ lati ma gba wọn laaye lati lọwọ si iwa jagidijagan lasiko oṣẹlu to wa nita yii.

Ana tii ṣe Wẹside ni Erelu Bisi Fayẹmi sọrọ yi niluu Abuja nibi ipade awọn adari lobinrin, iyẹn Forum of Women Leaders lẹka iṣẹ ijọba ati aladani kaakiri orileede yi, eyi ti wọ ṣe lati fi gbe ipa tawọn obinrin nko nipa iwa alaafia lasiko oṣelu larugẹ.

Agbekalẹ ajọ naa la gbẹ pe ko ṣẹyin ajọ awọn obinrin ilẹ Amẹrika (UN Women), orileede Naijiria ati igbimọ iṣọkan ilẹ Afrika lapapọ.

Erelu Fayẹmi sọ pe awọn obinrin le ko ipa to jọju lasiko oṣelu, paapaa lasiko idibo to n bọ lọna yi nipa fiforukọ silẹ gẹgẹ bi oludibo, ki wọn si jade lọọ dibo fun ẹni ti ọkan wọn yan, ati paapaa nipa kikilọ fawọn ọkọ atawọn ọmọ wọn pe ki wọn ma ṣe lọwọ ninu iwa jagidijagan, tabi iwa ipanle lasiko idibo.

Ninu ọrọ agbẹnusọ obinrin akọkọ nipinlẹ Ekiti, Erelu Fayẹmi ti amugbalẹgbẹ ẹ lẹka eto iroyin ati bo ṣe n lọ ẹ, Arabinrin Funmi Ajala ṣe sọ, o ni aṣeyori eto idibo to n bọ lọna yi wa lọwọ ipa tawọn obinrin kaakiri Naijiria yoo ko.

Idi ni pe, o wa lọwọ bawọn ba ṣe le ṣi awọn ọkọ atawọn ọmọ wọn lọkan lati ma lọwọ ninu iwa ibajẹ to maa n ṣẹlẹ lasiko idibo, eyi ti wọn n pe ni Electoral Violence.

Bakan naa lo tun gbawọn to n lo ẹrọ ayelujara lamọnran ki wọn dẹkun lati maa pin ayederu iroyin kaakiri, nitori pe ijamba to pọ lo n ṣe layika ati agbegbe wa.

Lara awọn to wa nibi ipade naa ni Sẹnetọ Abiọdun Olujimi, Dọkita Rẹmi Ajibẹwa ti ajọ ECOWAS, iyawo gomina ipinle Katsina, Dọkita Hadiza Aminu Masari, Ọgbẹni Edward Kallon to jẹ adari ajọ United Nations Resident and Humanitarian lorileede Naijiria, atawọn min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI