OLOSELU TI KO BA LO OMO E FUN TOOGI LASIKO IDIBO, KII SE OMO NAIJIRIA GIDI - PRIMATE JOSIAH UDOFIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, January 11, 2019

OLOSELU TI KO BA LO OMO E FUN TOOGI LASIKO IDIBO, KII SE OMO NAIJIRIA GIDI - PRIMATE JOSIAH UDOFIA

Olori soosi ile Adulawo, iyen African Church kaakiri agbaye, Ololajulo Emmanuel Josiah Udofia ti je ko di mi mo fawon oloselu orileede Naijiria pe eyikeyi ti ko ba ti lo omo e fun toogi ninu eto oselu to n lo lowo yi, kii se omo Naijiria gidi, ko si nife awon araalu rara, bi ko se pe ara e ati ebi e nikan lo feran

Bee lo tun so pe ooloselu to ba loo gba agbara okunkun, tabi loo jeje nijoba okunkun yoo kabamo gbeyin aye e, nitori pee to oselu ko ye ko je nnkan ti won n fi agbara okunkun wa, bi ko se nnkan ti won gbodo gba Olorun laaye lati dari e.


Lai pe yi ni Ololajulo (His Eminence, Primate) Josiah Udofia ba olootu iwe iroyin AWIKONKO, Ogbeni Segun Okeowo soro naa ninu ofiisi e to wa ni eka olu-iya ijo naa to wa lagbegbe Sam-Ewang niluu Abeokuta, nibi to ti n so awon ileri ti Olorun se fun orileede yi lodun 2019.

Agba ojise Olorun ti Olorun n gba owo e sise aami ati ise iyana, ninu oro e lo ti je ko ye awon eeyan pe odun 2019 je odun ti Olorun yoo da awon eeyan sile ninu igbekun ti won wa, ti won yoo si gba idalare, paapaa itusile atigbadegba.

Wonyi ni ohun ti iranse Olorun naa so;

NIPA ODUN 2019
E je ka dupe lowo Olorun alaaye to so wa titi di asiko yi.  Pelu ogo Olorun, odun 2019 gege bi onka ti Olorun gbe kale se so, yoo je odun ibukun fun awon omo e nitori pe Olorun ko daruko nnkan ti ko dara ninu odun yi sinu onka e. e maa ri i pe nigba ti Olorun da ile aye, gbogbo nnkan to da sibe, daradara ni. Gege bi nnkan ti Olorun fi han mi, odun tawon omo Olorun yoo ko ere to po ni, paapaa awa ta a gbagbo daadaa ninu ohun ti Olorun le se. Odun 2019 je odun itusile atigbadegba (Unseasoned Freedom), eyi ti Olorun fun wa lati inu iwe Joobu ori kokandilogun ese karundinlogbon (Job 19:25). Eyi tunmo si pe niwon igba ti Oludande mi ba si n be, emi yoo maa je anfaani itusile atigbadegba alailafiwe, ominira atigbadegba, ibukun atigbadegba. Jesu ti san gbogbo gbese wa lori igi agbelebu fun idande wa.

Mo fe e so fun gbogbo awon omo orileede Naijria atawon to n gbo mi bayii pe, ki won too le je igbadun idande ati itusile atigbadegba, eyi ti Olorun ti yonda fun wa, a ni lati je ore Olorun, a ni lati jowoo ara wa sile fun u, ki a si maa ba a se ore timo-timo. E je ki n fi ore molebi se apeere, bi e ko ba si ninu ebi kan, e ko le je anfaani tabi mo ohun to n sele nibe, ayafi ti e ba darapo mo iru ebi bee, nitori naa, awon eeyan gbodo darapo mo ebi Olorun ki won to o le je anfaani ti Olorun ti da sita fawon eeyan lodun 2019 ta a wa yi.

Ki a si to o le darapo mo ebi Olorun, afi ki iru eni bee gba Jesu Kristi gege bi Oluwa ati Olugbala e, nigba ti won ba ti se eyi, Olorun yoo so iru eni naa po mo awon ta a ti yan lati orun, ki won le bunkum fun un, idi ni yii ti bibeli fi so pe ‘Nitori naa bi enikeni ba wa ninu Kirisiti, o ti di eda tuntun, ohun atijo si ti koja lo’. Bakan naa la tun gbodo nigbagbo Olorun, nitori ti bibeli so pe ‘lai si igbagbo, ko see se lati wu Olorun’, bee la tun gbodo maa gbonran si Olorun lenu, ka si maa tele oro e. Bi a ko ba gbonran, ko si ba a se fe e je igbadun awon ibunkun ebun to fi sile fun wa.

E gbagbe nipa asotole tawon wolii kan n so sita npe odun yi yoo je odun wahala ati iponju, Olorun ko so bee, nitori pe ko lo nilana ohun ti bibeli la kale, mi o le tele, mi o si le gba won gbo nigba to je pe Olorun ni baba wa, to si ti seleri fun wa titi de opin aye, ko seleri iwa laaye e fungba die fun wa, titi lai lo pe e.

OSELU ORILEEDE NAIJIRIA
Mo ni opolopo nnkan lati so nipa oselu orileede yi, sugbon lakoko, maa koko rawo ebe sawon oloselu patapata, paapaa awon to n jade dupo eyikeyi lati mo pe oselu tabi eto idibo ko ye ko je bi won ko ba wole, ki won bere sii fa wahala, tabi ko je pe dandan ni won gbodo yege ni tipatipa. O gbodo nnkan bii ere idaraya, ati nnkan ti won gbodo gba Olorun laaye lati dari. Gbogbo wa la gbodo gba Olorun laaye lati je ko tuko eto oselu wa, ki Olorun le foju aanu e wo wa.

Nigba ti won ba pa olorun ti segbe kan, igba yen la maa rii pe won a maa se nnkan to wu won, eyi ti ko ba ife Olorun lo. Kii se gbogbo eeyan lo le di gomina, omo ile igbimo asofin, asoju leekan soso, sugbon mo gbagbo pe Olorun ni eto otooto fun onikaluku. Gbogbo wa la gbodo jokoo, ka gbadura lati beere lowo Oloun nipa eto to ni fun enikookan wa.

Awon oloselu gbodo mo nnkan daju pe ‘Ibi teeyan se pamo, maa n tele won kaakiri, paapaa leyin ti won ba lo’. Ohun ti onikaluku gbodo mo ni pe nnkan ti won ba gbin naa ni won maa ka. Eni to ba paaya ko too le yege ninu idibo, keni naa mo pe inu ewu ni aye oun wa. Eni to ba loo gb agbara okunkun lati fi bori idibo, won gbodo mo pe lojo kan, awon yoo san an eje naa pada, ati pe won gbodo mo pe ohunkohun ti won ba gba lowo esu, esu ko le fun won l’ofee. Dandan ni ki won san an pada, abamo si ni yoo je fun iru eni bee, nitori pe o le je asiko tiru eni bee ba n jegbadun ibunkun to gba lowo esu naa lowo ni esu maa de lati gba eje e pada. Eni naa si le fe e fi nnkan min in duro, sugbon ki esu so fun un pee mi e loun fe e gba.

Mo tun maa n so fawon oloselu ni gbogbo igba, pe ki won ye e lo awon odo gege bi toogi, di po bee, ki won lo awon omo won. Oloselu ti ko ba ti lo omo e gege bi toogi, kii se omo Naijiria gidi. Nigba ti oloselu ko ba le lo omo won fun toogi lasiko oselu, ki lo de ti won n lo omolomo, nitori pe nnkan teeyan ba le gba mora ni ko se fun eda egbe e. ti won ba a fe e lo omolomo, o ye ki won fi omo ti won naa siwaju, ti won ko ba ti le se bee, won gbodo lo omo eda egbe won gege bi toogi lasiko oselu to n lo lowo yi, tabi oselu ojo iwaju.

Bakan naa ni mo fe e rawo ebe sawon oloselu pe ki won gba idije yi pelu ife ara won, ki won si mo pe a ko ni orileede min in, bi ko se orileede yi kan soso ti Olorun fun wa lo. A si gbodo maa gbadura fun alaafia orileede yi, nitori pe bi a ba pa Naijiria ti lati maa gbe wahala lori soke, o tunmo si pe awon ti won n gbe wahala soke naa ni yoo fi emi won san an, nigba ti won ba n kore irugbin won.

Fawon oludibo patapata bakan naa, mo fe e be won pe ki won ma se ta oogun ibi (birthright) won. Mo si fe ki won fi apeere Isau tinu bibeli se apeere nigba to ta oogun ibi nitori ebi n pa, nigba to maa nilo e pada, asiko ti koja, ko see se fun mo, bo tile je pe pelu omije lo fi ta a, sugbon sibe, ko si atunse fun un. Olorun igba naa lo si wa lori ite bayii, aye igba naa lo si wa bayii, ko yi pada. Bi e ba ta ojo ola yin ati tawon omo yin nitori egberun lona ogun tabi egberun lona ogbon, bo si se egberun lona aadota ni, e mo daju pe nigba ti asiko atubotan ba de, ko si bi e se fe e sa fun un.

Bi e ba fe e dibo, e dibo fawon to le se e, iyen awon to se e fokan tan, ti won ni iberu Olorun lokan, ti won si nife orileede Naijria lokan. E ma dibo fenikeni nitori awon nnkan ti won n gbe wa fi tan yin je. Nigba ti e ba n pariwo pe ijoba ko pese ise, ti e si tun gba eni ti ko le se nnkankan laaye lati wole idibo, o ye ki e mo pe bawo le se fe ki eni to ti na gbogbo owo e fun un yin se nnkan ti e n fe, bawo le se fe kiru eni bee pese ise fawon omo yin, o tunmo si pee yin naa ti da si isoro aisi ise lorileede yi niyen.

Owo gbogbo oludibo ni Olorun yoo ti beere idi ti orileede Naijiria fi ri bayii basiko naa ba to. Mo fe e ro gbogbo eeyan pe ki won je ki alaafia joba ni gbogbo ibi kaakiri. E je ka dibo fawon ta a mo pe Olorun lo ran won si wa.

NIPA AWON AYEDERU ASOTELE
Mo fe e gbawon araalu lamonran pe ki won sora daadaa nitori bi enikeni ba soro sita nipa nnkan to fe e je, nigba ti Olorun ko ba ti soro, enikeni to ba so nnkan ti Olorun ko ba so, Olorun funra e ti so ninu bibeli pe ‘egbe’ ni fun iru eni bee.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI