ASIRI PASITO SOOSI CAC TO FOMODUN MERINDINLOGUN LOYUN TU L’AKURE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 10, 2019

ASIRI PASITO SOOSI CAC TO FOMODUN MERINDINLOGUN LOYUN TU L’AKURE


Se lo dabi eni pe ofin orileede Naijiria ko fese mule rara, lori basiri awon iranse esu ti won nforuko Olorun boju se n fojoojumo tu, paapaa bi iwa agbere ko se dinku ninu ijo Olorun.

Lojo Wesde ana nileese sifu difensi nipinle Ondo foju baale ile kan, Ogbeni Josiah Akinsuyi ta a gbo pe oun ni pasito soosi CAC kan to wa niluu Akure, eni ti won loo fomodun merindinlogun loyun osu merin han fawon oniroyin.

A gbo pe o ti pe ti Josiah ti kona fun omo naa ta a foruko bo lasiri, titi tomo naa fi loyun mon on lowo. Bomo naa se loyun la gbo pe o loo salaye fun Josiah pe oun ti loyun, sugbon ti pasito naa ni se lawon yoo yo, ati pe ko gbod so fenikeni.

Nigba tasiri maa tu, baba omo naa lo sakiyesi awon ayipada kan lara omo e, leyin ayewo ni won sakiyesi pe omo naa ti loyun, eyi lo fa a tokunrin naa fi gba ileese sifu difensi lo lati loo fejo sun.

Awon sifu difensi la gbo pe won loo gbe pasito naa nile, ti won loo si paro pe ko ri bee, won fe e ba oun loruko je ni, sugbon leyin e lo pada jewo pe looto ni, ati pe ise esu ni.

Ayewo tawon sifu difensi se gan an lo je ki won mo pe oyun osu merin lo wa lara omo naa.

Iwadii si n lo lowo titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI