Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
Bi awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Action Democratic Party (ADP) to je ẹgbẹ Babayẹmi, ṣe n
fojoojumẹ ṣeleri atilẹyin wọn fun un,
naa lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu mi-in
ti wọn n gbe lagbegbe naa n sọ pe kii ṣe ọrọ ẹgbẹ oṣelu n’idibo to n
bọ yii, Babayẹmi nikan
nipo naa tọ si.
Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Social Democractic Party (SDP) ko kan tiẹ fi ọrọ naa bo
rara, wọn ni ko si oloṣelu mi-in to
kunju oṣunwọn iṣẹ naa ju
Babayẹmi lọ, wọn si sọ pe oun
lawọn yoo dibo fun lọjọ kẹrindinlogun
oṣu keji ọdun yii.
Fọfọ ni
ori papa isere ileewe St Anthony School, lagbegbe Oke-Bode nilu Iwo kun lopin
ose to koja nibi eto asekagba idije boolu ti won pe ni Prince Dotun Babayemi
Youth Football Competition, eleyii to waye laarin awon egbe agbabolu niha
Iwo-oorun Osun, nibi ti Rovet FC tilu Iwo ti fagba han Hon.Shakor FC tilu Ede
pelu ami ayo meta si odo.
Awon omo
egbe oselu SDP lo asiko idije naa lati fidi atileyin won mule nita gbangba fun
Omooba Babayemi. Igbakeji alaga egbe oselu naa nipinle Osun, Ogbeni Folaranmi
Hamzat lo obitibiti awon omo egbe naa sodi lọ sibẹ.
Folaranmi
ni ko si nnkan tawon ri lara Babayemi ju iwa otito, eyi to se fokantan ati pe
lẹyin ti awon yen ipile awon oludije to ku wo, Babayemi nikan lo kunju osunwon
lati soju nile igbimo asofin agba orileede yii.
O lo asiko
naa lati parowa fun gbogbo awon eeyan agbegbe ọhun lati fowosowopo pelu Dotun
Babayemi lori erongba re, bee ni won gba awon ti ori ṣẹgi ọla fun lorileede yii
lati fi Babayemi sawokose nitori pe aimoye awon onirobinuje okan lo ti dun ninu.
Gbogbo
awon agbaagba ti won soro nibe ni won so pe laisi ariyanjiyan kankan rara,
Omooba Babayemi yoo tayo awon oludije to ku nibi idibo osu keji ohun.
Won salaye
pe ko si eka igbe aye kankan ti Babayemi ko fowokan ninu aye tolori-telemu nibe
laika ti egbe oselu tabi esin si rara, bo se sise ribiribi leka eto ilera, lo
ran ọpọ omo lowo lenu eko won, bee ni awon elesinjesin je anfaani Babayemi, o
si daju pe yoo te siwaju to ba le de ipo giga naa.
Asaaju
egbe oselu ADP lorileede yii, Alhaji Moshood Adeoti lo ko awon omo egbe oselu
ADP sodi lo sibi eto naa, bakan naa ni egbe akoroyin ere idaraya ti eka ipinle
Osun fun Babayemi ni ami-eye fun atileyin re lori nnkan to nii se pelu ere
idaraya nipinle Osun.
Awon
alakoso egbe oselu Social Democratic Party (SDP) ti won wa nibi eto naa lati
fontẹ lu Babayemi ni alaga won niha Iwo-oorun Enjinia Adetoye Ogungboyega,
olori awon obinrin lagbegbe naa, awon alaga nijoba ibile Ayedaade (Hon Ojo
Kamorudeen Elegunmeje), Ayedire (Alhaji Hon. Abideen Amusan), Iwo (Hon Alhaji
Akande Akeem), Ede North, Ede South (Alhaji Nureni Durodola Afebioye), Egbedore
(Alhaja Isiaka Amina) ati Ejigbo (Hon. Oloyede Odunayo).
No comments:
Post a Comment