ỌNNỌGHẸN: IGBESẸ TI KO BA OFIN MU NI BUHARI GBE – ALAGA ẸGBẸ OṢELU UDP - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 29, 2019

ỌNNỌGHẸN: IGBESẸ TI KO BA OFIN MU NI BUHARI GBE – ALAGA ẸGBẸ OṢELU UDP

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta

Alaga patapata fun ẹgbẹ oṣelu United Democratic Party, UDP, Oloye Austine Okoye, ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ti Aarẹ orileede yi, Ọgagun Muhammadu Buhari gbe latari bo ṣe yọ adajọ agba orileede yi, Onidajọ Walter Ọnnọghẹn nipo lojiji latari awọn ẹsun ti wọn fi kan an pe ko jẹwọ gbogbo dukia ẹ tan ki wọn too yan an.

Lọjọ Fraide ọsẹ to kọja yi ni Aarẹ Buhari kede sita fawọn araalu pe oun ti jawe lọọ jokoo sile ẹ fun adajọ agba naa, eyi lo si ti fa oriṣiriṣi wahala laari ẹka eto idajọ, oṣelu, bẹẹ lawọn eeyan jankan-jankan naa ko dẹkun lati maa bu ẹnu atẹ lu igbesẹ Aarẹ naa.

Lọjọ Mọnde ana ni Oloye Okoye to jẹ alaga lapapọ ẹgbẹ oṣelu UDP lorileede yi naa b’AWIKONKO sọrọ niluu Ọta nipinlẹ, nibi ipolongo imurasilẹ idibo gomina to n bọ nipinlẹ Ogun, eyi ti wọn ṣe fun adije sipo labẹ ẹgbẹ oṣelu naa, iyẹn Oloye Arabinrin Jackie Adunni Kassim, nibẹ lo ti mẹnuba awọn iwa to ku diẹ kaato, eyi to n lọ lagbo oṣelu orileede yi.

Okoye sọ pe “Igbesẹ naa ko ba ilana ofin mu rara, paapaa fun awa ta a jẹ agbẹjoro, ibanujẹ lo jẹ fun wa pe iru nnkan bayii n ṣẹlẹ niru asiko ọlaju ta a wa yii, ati pe niru orileede Naijiria to n ri ara ẹ gẹgẹ bi asiwaju awọn orileede ilẹ adulawọ (Afrika) ni wọn ti n tẹ ofin mọlẹ ṣibaṣibo.

“Gbogbo awọn ọmọ orileede Naijiria patapata ni wọn gbọdọ dide niru asiko bayii lati ja fun ẹtọ naa, nitori pe nigba ti awọn apaṣẹ ba de, awa ọmọ Naijiria yi ni yoo jiya ẹ. Nnkan to ṣẹlẹ yi jẹ ibanujẹ pupọ fun ofin wa, to si tun jẹ itiju fun lilo agbara wa, ati fifi eto iṣejọba awaarawa si ojuṣe.”

Nigba to n sọrọ lori ibẹrun awọn eeyan pe o ṣee ṣe ki wọn yi ibo ọdun 2019, alaga naa sọ pe “Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yi, mi o ni fẹ ẹ ka ẹnikẹni bo ya aya wọn n ja, nitori pe igi inu igbi nikan lo maa gbọ pe wọn ge igi lẹgbẹ oun, to si tun maa duro, ko da bi aro, gan an ba gbọ pe wọn fẹ ẹ pa oun, o maa wa gbogbo ọna lati salọ.

“Nnkan ta a ti ri atawọn nnkan ta n ri lojoojumọ lorileede yi ti fi ye wa pe gbogbo nnkan lo ti bajẹ, asiko yi kii sii ṣe asiko tẹnikẹni le maa sunnu si, asiko ipenija nla la wa lorileede yi, a si gbọdọ rii pe a yanju ẹ daadaa, ki nnkan le pada bọ sipo, nitori pe ọpọ igba lati fi erongba wa han nipa ofin to de ajọ aleto idibo, iyẹn INEC to tun jẹ pataki, nitori pe ọna lati gbe ọkan kuro nibi to yẹ lawọn nnkan min in to n ṣẹlẹ lati ma jẹ kawọn eeyan okodoro nnkan ta n koju.

“Bawo lẹ ṣe maa so fun mi pe eeyan wa a dibo, ero ti wọn fi n yẹ kaadi wo ko da ẹni to ni kaadi mọ, ẹ si gba iru ẹni bẹe laaye lati dibo, bawo lẹ ṣe maa sọ fun mi pe ẹni kan ji kaadi idibo yin, wọn si gba yin laaye lati dibo, bawo lẹ ṣe maa mu agbegbe tawọn eeyan yoo ti dibo, tawọn to wa lagbegbe naa ko si nii mọ.

“Wọn ni yiyẹ awọn ti yoo dibo ni kaadi idibo alalopẹ, PVC wa fun, wọn tun ni awọn ilana kan wa tawọn eeyan yoo ṣe, ẹ ba mi beere boya gbogbo ẹgbẹ oṣelu ni wọn mọ nipa ẹ. To ba wa a di ọjọ idibo, wọn a wa maa sọ fawọn kan pe wọn ko lanfaani lati dibo, awọn kan ni wọn le dibo.

“Bawo lẹ ṣe fẹ ka gbagbọ pe wọn ko nii yi ibo, awọn ti wọn si n ni ifura yi, mi o bu ẹnu atẹ lu wọn, nitori pe nnkan to dara ni. Ti ajọ INEC ba mọ nnkan ti wọn n ṣe, ti wọn si ṣe e lasiko, lati da igboya wọn pada sọkan awọn araalu, inu wọn yoo dun. Itẹsiwaju lo yẹ kijọba jẹ, ko nii ṣe pẹlu ẹni to ba wọle, bi ẹ ba wọle, ẹ maa tẹsiwaju lati maa ṣe ifẹ ọkan awọn ọmọ Naijiria.

“Bo ṣe yẹ ki nnkan maa lọ niyẹn, a n ja fun, a si tun ma maa tẹsiwaju lati ja fun un ni.”

Bakan naa nigba to n sọrọ nipa bi ẹgbẹ naa yoo ṣe gba ijọba lọdun 2019 ti a wa yii, paapaa nipinlẹ Ogun, Oloye Okoye ni “Bi ẹyin naa ba ri bi nnkan ṣe n lọ, ẹ maa rii pe adije wa, Oloye Jackie Adunni jẹ ẹni tawọn araalu fẹran, to si ti ṣe oriṣiriṣi anfaani fawọn eeyan. Ẹni to ti mu awọn eeyan kuro ninu iṣẹ ati oṣi ni, to si tun sunmọn awọn eeyan daadaa lai ṣe ojuṣaaju ẹnikẹni.

“O wa a ku sawọn araalu lọwọ lati yan ẹni ti wọn fẹ, ṣugbọn mo nigbagbọ pe to ba jẹ ifẹ Ọlọrun ni, to si tun jẹ ifẹ awọn ọmọ ipinlẹ Ogun, yoo de ipo gomina naa, nitori pe gẹgẹ obinrin ati abiyamọ tootọ, o kun oju oṣuwọn lati ṣe e.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI