Adije sipo gomina nipinle Ogun labe egbe
oselu Alliance for New Nigeria, ANN, Ogbeni Ademola Ogunbanjo ti so pe kawon
omo orileede Naijiria loo fokan won bale, ki won si ma se gbe okan won soke
latari idibo to n bo lona yi nitori pe owo Olorun oga ogo ti wa ninu e, to si
ti pari ise patapata.
Ogunbanjo |
Lai yi ni Ogunbanjo b’AWIKONKO soro niluu
Abeokuta, nibi to ti so pe ko si nnkan to n ba oun leru lati dije dupo gomina
ipinle Ogun, paapaa bawon kan se n so pe awon alagbara ti pari ise lati yi esi
idibo sodo won.
O ni pelu gbogbo nnkan to n lo yi, ko si
nnkan to di awon lowo lati maa polongo erongba won fawon oludibo lai wo awon
nnkan tawon alagbara orileede yi n se nipa eto idibo to n bo lona losu keji
odun yi.
O ni “Awon kan n so pe won yi esi ibo ki ojo
idibo to o de, awon kan ni won ti ko o sile, awon kan ni won ti gbe esi ibo
sita, a ni itara pelu nnkan ta a n se, a si tun ma a tesiwaju lati maa se ti
wa, ka si tele ilana, a maa sise ti wa, nitori pe owo wa lo wa, a ko fi nnkan
ti enikeni n gbero se.
“Bi e ko ba i tii sakiyesi titi dasiko yi pe owo
Olorun wa ninu idibo odun 2019, e lo wo nnkan to n lo ninu egbe oselu APC ati
PDP lasiko yi, ki e wa so fun mi bi igbimo ota ko ba ti daru, e maa rii pe owo
Olorun ti wa ninu eto oselu Naijiria.
“Apolo n bu omi rin, sugbon Olorun lo n bukun
un, awa n furugbin, kawon to ba si gbagbo ninu wa maa bu omi rin wa. Lati maa
gba ijoba apapo lamonran lori nnkan to ye ki won se je nnkan atijo ti ko lasiko
mo, amonran awon eeyan ko ni apeere kankan sijoba. E je ki won gbe agbekale won
lati yi esi ibo sile, e maa rii pe leyin gbogbo e, gbogbo ogbon ati imo won maa
di ode.
“Opo wa la ti n fi aimoye odun gbaawe ati
adura pe ki Olorun yi igba rere pada fun wa, pe ki Olorun da si oro Naijiria,
ko si eni naa lorileede yi ti kii gbadura, mo fe e so fun un yin pe adura wa ti
gba nitori pe Olorun ti setan lori oro wa.
“Nnkan to ku ka se ni pe ki gbogbo wa dide loo
dibo lati doju ti awon ota Naijiria, a gbodo le fa eni to le se e kale. Ojoojumo
ni mo n lo kaakiri lati bawon eeyan soro lati ojule kan si ekeji, kaakiri ijoba
ibile to wa nipinle Ogun. Mo lo sibi kan lai pe yi, ibi ti mo ti n bawon eeyan
soro ni won ti so pe Eerin Lakatabu pa eeyan meji losu meloo kan seyin, ibe ni
mo ti mo pe a ni Eerin nipinle Ogun.
“A ko ni agbegbe tawon eranko n gbe lati maa
fi pawo wole, owo tijoba Rwanda n pa lori eranko ti won n pe ni Gorila ko din
ni irinwo milionu dola ($400m) lodoodun. Awa ni Eeri ni Magboro, J4 ati eyin
Osun, a ko si se nnkankan sii lati maa pawo wole fun wa. Gbogbo ibi ti mo n lo
ni mo ti n bawon eeyan soro, ti mo n soro sinu okan won, nitori nnkan to se pataki
niyen.
“Opo awon ti won fe e di gomina ipinle Ogun
lo je pe won ko ni afojusun kan ni pato, adije sipo gomina kan ni won n foro wa
lenu lori telifisan lai pe yi pe ki lo fe e se fawon omo ipinle e, se lo bere
sii wo inu iwe to ko o si. Ko ye ki eni to mo nnkan to fe e se tun maa ko o
sile, o ye ko ti mo gbogbo e, ko da, bi won ba ji loju ooru, o gbodo le so o.”
Ademola Ogunbanjo wa a gbawon omo ipinle Ogun
lamonran pe ki won dibo yan oun nitori pe awon idagbasoke toun fe e mu wo
ipinle Ogun yato eyi tawon to ti se e tele atawon ti won ko ni erongba kan ni
pato, bi ko se lati ji owo ko lo.
Bee lo gbawon eeyan lamonran pe ki won jade
dibo fun eni ti okan won n fe, ki won ma si gba owo ki won to o dibo lojo
idibo.
No comments:
Post a Comment