ỌWỌ TẸ TẸGBỌN TABURO TI WỌN FẸ Ẹ KO TRAMADỌL LỌ FAWỌN ẸLẸWỌN NI KUJE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, January 23, 2019

ỌWỌ TẸ TẸGBỌN TABURO TI WỌN FẸ Ẹ KO TRAMADỌL LỌ FAWỌN ẸLẸWỌN NI KUJE


Bi kii ba a ṣe pe awọn wọda ti wọn ṣọ awọn ẹlẹwọn to wa ni Kuje, niluu Abuja ko sun asunpara ni, o ṣeeṣẹ ki tẹgbọn tabubro kan ti wọn pe orukọ wọn ni Blessing ati Victoria Chinwuba ti wọn gbiyanju lati ko oogun tiramadọ wọnu ọgba ẹwọn fawọn ẹlẹwọn to wa nibẹ.

Ohun ta a gbọ ni pe inu ọra ti ounjẹ awọn ọmọde, iyẹn noodles la gbọ Victoria ko awọn oogun tiramadọ naa si, to si gbe e fun ẹgbọn ẹ Blessing pe ko loo gbe e fun ọrẹkunrin wọn toun wa lọgba ẹwọn nibẹ, iyẹn John Ifeanyichukwu.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ojulalakan-finṣọri, iyẹn Fijinlante lo tu aṣiri naa sita. A gbọ pe ṣe ni Fijilante naa gba baagi ti Blessing gbe danu, to si yẹ ẹ wo finni-finni, lẹyin-o-rẹyin lo ṣakiyesi pe oogun oloro lo wa nibẹ.

Lẹsẹkẹsẹ lo si ti pariwo sita fawọn yooku ẹ pe aṣiri ọdaran kan ti tu soun lọwọ, idi ni yii to fi muu lọ sọdọ awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn naa.

Agbẹnusọ fun ọgba ẹwọn Kuje, Ọgbẹni Humphrey Chukwuedo lo fi iṣẹlẹ naa sita fawọn akọroyin lọjọ Tuside ana.

Chukwuedo si jẹ ko di mimọ pe ileeṣẹ ti ko tẹgbọn taburo naa fun ileeṣẹ to n ri si gbigbe oogun oloro, iyẹn National Drug Law Enforcement Agency lati ṣe iwadii wọn siwaju sii, ki wọn si fẹsẹ ofin mu wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI