WỌN JU ỌBA AYETORO SẸWỌN L’ONDO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 16, 2019

WỌN JU ỌBA AYETORO SẸWỌN L’ONDO

Ile ẹjọ majisireeti to fikalẹ siluu Akurẹ nipinle Ondo ti paṣẹ pe Ọba Oluwambẹ Ọjagbohunmi tiluu Ayetoro nijọba ibilẹ Ilajẹ ṣi lọ maa gbatẹgun lọgba ẹwọn titi di ọjọ kẹrinlelogun oṣu yi latari ẹsun idigunjale ati dida wahala silẹ laarin ilu ti wọn fi kan an.

Ade Ọba
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni Kabiyesi naa atawọn kan awọn ti na papa bora lọọ digun jale pẹlu ibọn, ada atawọn nnkan ija oloro. Awọn eeyan marun-un ọtọọtọ la gbọ pe Kabiyesi atawọn ẹmẹwa ẹ lọ ọ digun ja lole obitibiti owo ati dukia laipẹ yii.

Yatọ si eyi, agbẹjọro fawọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Ọlatunji Kazeem to fẹsun kan Ọba Ọjagbohunmi sọ pe ẹsun ti ileeṣẹ wọn fi kan Ọba naa tako ofin lilo ibọn lorileede yi tọdun 2004.

O ni yatọ sawọn ti Ọba Ọjagbohunmi atawọn ẹmẹwa ẹ ja lole yi, wọn tun lọ ọ gbimọ pọ ja ọkunrin l’ole owo ti ko din ni ẹgbẹrun lọna aadọjọ (160,000), bẹẹ ni wọn tun ji ẹrọ amunawa, iyẹn jẹnẹretọ ẹ.

Bẹẹ lo tun sọ pe Kabiyesi atawọn eeyan ẹ yi tun yinbọn fun ọkunrin kan ti wọn pe ni Olu Obolo ni ẹsẹ lasiko ti wọn n fa wahala, o ni gbogbo ẹsun yi lo tako iwe ẹsun ọdaran tipinlẹ Ondo, t’ọdun 2006.

O wa rọ ile ẹjọ naa lati ma gba jẹ ki ẹnikẹni gba beeli Kabiyesi naa digba ti wọn yoo tubọ fi pari awọn iwe ẹsun e.

Adajọ ile ẹjọ naa, Onidajọ Maymi lanipkun wa a paṣẹ pe kawọn ọlọpaa ṣi lọ ọ fi Ọba alaye naa pamọ sọdọ wọn titi di ọjọ kẹrinlelogun oṣu yi, igbẹjó min-in yoo waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI