WỌN TUN TI YỌ IGBAKEJI ABẸNUGỌN ILE IGBIMỌ AṢOFIN IPINLẸ EKITI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 17, 2019

WỌN TUN TI YỌ IGBAKEJI ABẸNUGỌN ILE IGBIMỌ AṢOFIN IPINLẸ EKITI

Titi di bi ẹ ti n ka iroyin yi, ko tii sẹni to le sọ ibi ti wahala ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ekiti yoo jasi latari wahala tawọn aṣofin naa n ba ara wọn fa, paapaa bi wọn tun ṣe yọ igbakeji abẹnugọn olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Ọgbẹni Ṣẹgun Adewumi.



Gẹgẹ b'AWIKONKO ṣe gbọ, kii ṣe akọkọ re e ti wọn yoo yọ Ọgbẹni Ṣẹgun nipo, wọn ti figba kan ri yọ okunrin naa latari awọn ẹsun iṣowo kumọ-kumọ ti wọn fi kan an, iyẹn lasiko ijọba Ayọdele Fayọṣe.

Adewumi to n ṣoju agbegbe kin-ni-in l'ẹkun Ekiti West (Constituency I) la gbọ pe ọjọ kẹfa, oṣu kẹfa ni wọn yan an gẹgẹ bi ẹni keji nile igbimọ naa.

O ku igba diẹ ki wọn bura fun Gomina Kayọde Fayẹmi gẹgẹ bii Gomina la gbọ pe wọn da a pada.

Ni bayii, Ọnarebu Ọlapọsi Ọmọdara toun n ṣoju agbegbe kinn-in-ni l'ẹkun Irẹpọdun/Ifẹlodun ni wọn yan bayii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI