AGABAGEBE NLA: Ẹ GBỌ NNKAN TI GOMINA AMOSUN TUN SỌ O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 26, 2019

AGABAGEBE NLA: Ẹ GBỌ NNKAN TI GOMINA AMOSUN TUN SỌ O

...awọn ọta gbimọ lati jami kulẹ, ṣugbọn...


Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta

Gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun ti sọ ọ di mimọ pe oun yoo bẹrẹ ipolongo idibo fun adije sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APM, Ọnọrebu Adekunle Akinlade lati tako adije sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Ọmọba Dapọ Abiọdun.

Gomina Amosun lo sọrọ naa lọjọ Mọnde ana lasiko to n bawọn akọroyin ijọba sọrọ niluu Abẹokuta lẹyin to jawe olubori.

Fawọn to ba oṣelu ipinlẹ Ogun daadaa, paapaa idibo to kasẹ nilẹ lọjọ Satide to kọja yi, Gomina Amosun lo gbegba oroke nibi idibo Sẹnetọ ti Aarin Gbungbun ipinlẹ Ogun (Ogun Central), to si fi ẹyin awọn bii Ọnọrebu Titi Oseni Gomez ti ẹgbẹ oṣelu ADC, Apọsiteli Abiọdun Sanyaolu tẹgbẹ oṣelu PDP atawọn min in gbolẹ.

Iyalẹnu lọrọ naa jẹ fun pupọ ninu awọn to gbọ nnkan ti Gomina Amosun sọ, to si mu ki wọn maa sọ pe agabagebe ti Gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla n sọ gan an lo ṣẹṣẹ wa a foju han bayii.

Ninu ọrọ Gomina Amosun lo ti sọ pe “Inu mi dun fun abajade esi ibo to kọja yi, awọn eeyan ti jẹ anfaani nibẹ, bi ile aye ṣe ri niyẹn, awọn eeyan mọ ẹni tawọn n dibo yan ninu ẹgbẹ APC, o si foju han nigba ti esi ibo naa jade, bi ẹ ba yẹ ibo Aarẹ Buhari ati eyi to gbemi wọle wo, ẹ maa rii pe iyatọ diẹ wa nibẹ,

“Awọn ti wọn ko fẹ ka wọle niyẹn, awọn ti wọn nifẹ wa jẹ ida ọgọrin si aadọrun ninu ọgọrun, awọn ti wọn ko si nifẹ wa ko ju idamẹwa ninu ọgọrun lọ.

“Ẹ ma ro pe gbogbo eeyan ni yoo nifẹ yin, ko nii ṣe bi ẹ ṣe mọ nnkan ṣe to, eeyan ẹlẹran ara ni wa, awọn kan maa wa ti wọn ko nii nifẹ yin bi wọn ko ba korira yin, wọn ko ṣa a ni nifẹ yin ṣa a ni.

“Emi ko korira ẹnikẹni. Lootọ, mi o ka a si nnkankan pe wọn fẹẹ gbimọ pọ ṣiṣẹ lodi si mi, ṣugbọn bi ẹ ba ri abajade esi ibo yẹn, ẹ maa rii pe lootọ ni wọn gbimọ pọ lodi si mi, ṣugbọn Ọlọrun to n gbe inu mi ju Ọlọrun to n gbe inu wọn lọ.

“Bẹẹni, inu mi dun, mo fẹẹ ṣoju awọn eeyan mi, wọn ti fun mi ni ibo wọn, inu mi dun, mi o si le dupẹ lọwọ wọn tan.

“Lati oni lọ, a maa fi oni bọwọ fun ọkan lara wa to papoda ninu ijamba, a si dupẹ lọwọ akọwe ijọba wa fun ẹmi ẹ, a ko nii le bẹrẹ ipolongo idibo lonii, ati pe to ba di ni ọla, a maa bẹrẹ ni pẹrẹu fun oludije mi, oludije wa, Abdulkabir Adekunle Akinlade.

“Lati ọla lọ gbogbo awọn oludije sipo ile igbimọ aṣofin ni wọn ti gbaradi fun ipolongo idibo to n bọ lọna.

“Awọn eeyan ti jẹ mudunmudun ijọba APC, ko si wahala nibẹ nitori pe mo ti jade wa fun idibo to jẹ ti ẹgbẹ oṣelu APC nitori Aarẹ Mohammadu Buhari gbọdọ jawe olubori, a si ti ri i pe o ti ṣee ṣe.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI