WAHALA DE: NITORI GBESE TI GOMINA AMOSUN JẸ, WỌN FẸẸ TI IPINLẸ OGUN PA LỌJỌ FRAIDE ỌSẸ YI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 26, 2019

WAHALA DE: NITORI GBESE TI GOMINA AMOSUN JẸ, WỌN FẸẸ TI IPINLẸ OGUN PA LỌJỌ FRAIDE ỌSẸ YI


Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Gbogbo eto lo ti pari bayii fun ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Najiria lati ti gbogbo ipinlẹ Ogun pa pẹlu iwode ifẹhonu han ti wọn fẹẹ ṣe nitori bi wọn ṣe sọ pe Gomina ipinlẹ naa, Ibikunle Amosun jẹ awọn oṣiṣẹ lowo rẹpẹtẹ, ti ko si fẹẹ san owo naa ko too lọ.

Iwọde naa ta a gbọ pe alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, Kọmureedi Ayuba Waba fẹẹ lewaju ẹ ni wọn ti so pe ọjọ Fraide ọsẹ yi ni wọn fẹẹ ṣe kaakiri ipinlẹ Ogun, bẹrẹ lati ilu Abẹokuta to jẹ olu ipinlẹ naa.

Ninu lẹta ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ kọ ranṣẹ si Gomina Amosun lọjọ Wẹside ọsẹ to kọja, eyi ti ẹda ẹ tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yi ni wọn ti sọ pe koko iwọde naa da lori bi Gomina Amosun ṣe n ṣe awọn oṣiṣẹ niṣekuṣe.

Koko ọrọ ti wọn fi sọri iwọde naa ni wọn pe ni ‘Ẹ Gba Ipinlẹ Ogun’ (Operation Occupy Ogun State) pẹlu iwa Lilodi s’awọn oṣiṣẹ, iyẹn (Anti-Worker Actions) ti ijọba Gomina Amosun n hu nipinlẹ naa.

Ninu lẹta naa ni alaga patapata fawọn oṣiṣẹ orileede Naijiria, Ayuba Wabba ti sọ pe iwọde tawọn fẹẹ ṣe lọjọ Fraide ọsẹ yi yoo gba kawọn ti ipinlẹ Ogun pa titi ti Gomina Amosun yoo fi dawọn lohun nnkan ti wọn n fẹ.

Lara awọn nnkan ti wọn n beere lọwọ Gomina Amosun gẹgẹ bi wọn ṣe kọ ọ sinu lẹta naa ni owo osu ti Gomina jẹ wọn, owo ajẹẹlẹ ati owo alajẹṣẹku ti Gomina kọ lati fun wọn.

Eyi to tun jẹ koko inu ẹ ni bi Gomina Amosun ṣe kọ lati da alaga awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Akeem Ambali pada sipo to wa tẹlẹ ati tawọn oṣiṣẹ ti ileewe giga Tai Ṣolarin to wa niluu Omu-Ijẹbu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI