AKARIGBO TILẸ RẸMỌ LOUN YOO MU IDAGBASOKE BA IGBOKEGBODO ỌKỌ NIPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 2, 2019

AKARIGBO TILẸ RẸMỌ LOUN YOO MU IDAGBASOKE BA IGBOKEGBODO ỌKỌ NIPINLẸ OGUN



Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta

Akarigbo tilẹ Rẹmọ, Ọba Babatunde Adewale Ajayi ti sọ pe gbogbo agbara to ba wa nikawọ oun loun yoo lo lati rii pe idagbasoke de ba ipinlẹ Ogun, paapaa nipa igbodegboke ọkọ.

Ọba Ajayi lo sọrọ naa lasiko to n gba awọn igbimọ to n ri si igbokegbodo ọkọ nipinlẹ naa lalejo ni aafin ẹ to wa niluu Ṣagamu laipẹ yi.

Kabiyesi naa ni pẹlu ipo oun ati boun ṣe mọ awọn ọlọla kaakiri agbaye to, paapaa boun tun ṣe jẹ Ọba alaye nilẹ Rẹmọ, oun yoo rii pe awọn nnkan to le mu kawọn to n da ileeṣẹ nla-nla silẹ loun yoo gbe kalẹ.

Awọn igbimọ to n ri si igbokegbodo ọkọ, iyen State Bureau of Transportation (BOT) nipinlẹ Ogun la gbo pe wọn loo sabẹwo si Kabiyesi Akarigbo lati yẹ awọn bọọsi nla-nla to ṣẹṣẹ ra fun igbokegbodo awọn araalu wo, ati bawọn araalu ṣe tẹwọ gba a si.

Ninu ọrọ ti ẹ, amugbalẹgbẹ Gomina ipinlẹ Ogun lẹka igbokegbodo ọkọ, Amofin Gbenga Opẹsanwo ti Onimọ-ẹrọ Wale Ṣokunbi ṣoju fun gbe oṣuba kare fun Akarigbo latari bo ṣe da si ipenija to n koju igbokegbodo awọn araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI