Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
Pẹlu oṣelu
to n lọ lọwọ nipinlẹ Ọṣun bayii, iroyin
to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yi jẹ ko ye wa pe
asiko yi kii ṣe asiko to fararọ fun gbajumọ oṣere tiata tẹlẹ nni, Oloye Rotimi
Makinde rara, paapaa nidi oṣelu, ṣugbọn ta a gbọ pe o kan n fi ọrọ ara ẹ pamọ
sabẹ aṣọ ni.
Fawọn
to ba mọ Rotimi Makinde daadaa, ọkan lara awọn ogbontarigi gbajumọ oṣere tiata
t'awọn eeyan n gba ti ẹ gidi l'ọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Ọṣun naa, o si
ti n lọ bi ọdun mẹwaa bayii ti ọkunrin naa ti fiṣẹ tiata silẹ darapọ mọ oṣelu.
Aṣoju-ṣofin to n ṣoju awọn ara agbegbe Ifẹ South nile igbimo
aṣoju-sofin niluu Abuja tẹlẹ ni Rotimi
Makinde, awọn ipa ati idagbasoke to si ti mu ba agbegbe to ṣoju
tẹlẹ yi ko ṣe e fẹnu bu kere.
Ṣugbọn pẹlu iroyin to tẹ wa lọwọ, AWIKONKO gbọ pe nnkan
ko fara rọ fun ọkunrin naa, paapaa pẹlu bi oṣelu ipinlẹ naa ṣe n gbona jọjọ, to
si kọ lati sọrọ sita fawọn eeyan lati mọ ibi to ku sii.
AWIKONKO gbọ pe ọpọ awọn oloṣelu ni wọn ti wa n fi owo lọ
ọkunrin naa ko le ba a ran wọn lọwọ, bẹẹ la gbọ pe gbogbo ọna lawọn oloṣelu kan
n wa lati fi owo tan an jẹ, ki wọn le ba a ba orukọ ẹ jẹ lọjọ iwaju, ṣugbọn ti
wọn ni ṣe lo n kọ ọ si wọn lọwọ.
Rotimi Makinde, sọ pe o san foun lati ma gba owo naa lọwọ
awọn oloṣelu ẹlẹtanjẹ, ju lati gba owo naa tan, ki wọn wa a fi ba oun lorukọ jẹ
lọjọ iwaju, toun si n ṣajọyọ ẹ lọkan oun nikọkọ, lai jẹ kẹnikẹni mọ.
AWIKONKO gbiyanju lati ba gbajumọ oloṣelu naa sọrọ lati
mọ idi to fi dakẹ, ti ko fi sọrọ jade sita, oun ti ọkunrin naa sọ ni pe “Adan mi dorikodo, o n wo iṣe ẹyẹ. Bi a ko ba ni purọ, ta o si ni ṣ’eke, asiko yi ko faraarọ fun Ogbontagiri elere ori itage tẹlẹ to ti wa di oloẹelu nipinlẹ Ọṣun.
“Di dake lo yẹ
mi lasiko ti mo wa yii, ki ẹnikẹni ma ba a ri awijare tabi ri aheeso
kankan sọ nipa mi.”
No comments:
Post a Comment