APC, PDP ATI CUPP GBE INA WOJU INEC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 18, 2019

APC, PDP ATI CUPP GBE INA WOJU INEC

Niwọn igba ti ajọ INEC ti sun ọjọ idibo siwaju, awọn ẹgbẹ to n dije ninu idibo gbogboogbo ọdun 2019 ni Naijiria ti ni awọn ko ni tẹle aṣẹ ajọ INEC to ni ki ipolongo wa sopin ni ọjọbọ ọsẹ to kọja.

Awọn oludibo 
Lọjọ abamẹta to kọja ni alaga ajọ INEC, ọjọgbọn Mahmood Yakubu ṣalaye awọn idi ti wọn fi sun eto idibo naa siwaju to si ni gbogbo ipolongo ti wa sopin lọjọbọ ọsẹ kan naa.

Ẹwẹ ni ọjọ aiku ọsẹ ni ẹgbẹ APC, PDP to fi mọ apapọ ẹgbẹ to n jẹ CUPP ni laa, awọn yoo tẹsiwaju pẹlu ipolongo awọn.

Ninu iroyin kan latọdọ ẹka ede Hausa ti ile iṣẹ BBC ni alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Adams Oshiomole ati adari kan fun ipolongo Atku, Sẹnetọ Rabiu Kwankwaso ni ofin idibo faaye gba i[polongo ko to di wakati mẹrinlelogun ṣaaju ọjọ idibo.

Wọn ni "gbogbo eniyan lo mọ pe ipolongo ṣi le tẹsiwaju ko to ku wakati mẹrinlelogun ki idibo to waye niwọn igba ti wọn si ti sun idibo siwaju di ọsẹ kan, o yẹ ki awọn ẹgbẹ oṣelu tẹsiwaju pẹlu ipolongo wọn".
Media captionÀwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà fohùn ránṣẹ́ sí ìjọ̀ba tí yóò wọlé

Awọn alaga ajọ eleto idibo ti n ṣalaye kaakiri ibi ti awọn oniroyin ti kan si wọn wi pe ajọ eleto idibo laṣẹ lati ṣe awọn ofin fun eto idibo ṣugbọ́n awọn ẹgbẹ oṣelu ni laa, awọn yoo tẹsiwaju pẹlu ipolongo.

Kola Ologbondiyan to j akọwe apapọ gb oṣelu PDP niPDP kọ ohun to pe ni idari lọna aitọ lati dena ipolongo.

Ni ti Adams Oshiomole, o ni "INEC ko le ṣe lodi si ofin. Gbogbo eniyan lo mọ pe wakati mẹrinlelogun ṣaaju idibo ni ipolongo lee duro. Emi yoo tẹsiwaju pẹlu ipolongo tori bi a ko ba polongo, awọn eniyan ko ni jade wa dibo".

Bakan naa ni apapọ ẹgbẹ CUPP latẹnu agbẹnusọ rẹ, Imo Ugochinyere ni ki awọn eeyan rẹ ni ohun ti Yakubu n sọ ko ba ofin mu.

Pari pari ẹ, ajọ INEC naa ni "a o gbe igbesẹ ti yoo kasẹ ohun gbogbo nilẹ lonii".

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI