NITORI BABA SUWE, LIZ ANJỌRIN KI ORIN EPE ÒGÚN BỌ ẸNU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 19, 2019

NITORI BABA SUWE, LIZ ANJỌRIN KI ORIN EPE ÒGÚN BỌ ẸNU

Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun

Ko sẹni to le panude nigba ti wọn ri bi gbajumọ oṣere tiata, ọmọ bibi ilu Abẹokuta nni, Elizabeth Anjọrin, ẹni tọpọ awọn ololufẹ ẹ mọ si Liz Anjọrin ṣe ki epe bọ ẹnu, to si n fi ogun ṣepe fawọn to n bu ẹnu atẹ luu lori bi ko ṣe ran Baba Suwe lọwọ latari aisan to n ba po o.

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe Liz Ajọrin pẹlu awọn oṣere tiata ti Ọlọrun gba fun lasiko yi, to si lowo gidi daadaa lọwọ.

Laipẹ yi ọkan lara awọn to n tẹlẹ Liz Anjọrin lori ẹka ayelujara, Instagram bu ẹnu atẹ luu pe ko ran Alaaji Babatunde Omidina, iyẹn Baba Suwe lọwọ ninu ipo to wa, pẹlu bo ṣe lowo to.

Ọrọ yi bi Liz ninu gidi gan an, to si mu ko bẹrẹ sii sẹpe nla-nla, to tun mu awọn eeyan ranti bo ṣe padanu Mama ẹ, ti ko sẹni to dide iranlọwọ fun un, ati bo tun ṣe jẹ pe asiko kan naa ni wọn ji mọto ẹ salọ.

Liz Anjọrin sọ pe ko si iranlọwọ kankan nidi iṣẹ tiata bi ko ṣe pe oju aaye ni gbogbo wọn ṣe, ati pe ‘ṣiṣẹ ẹ, ko o gba owo ẹ’ lo wa nidi iṣẹ naa, lẹyin yẹn ko si nnkan min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI