Ọga agba
ileewe awọn ọmọ
ọrukan to wa
niluu Abeokuta, iyẹn Stephen Centre International, Rẹfurẹndi
Isaac Oluwọle Newton-Wusu ti foju bale ẹjọ latari ẹsun marun ọtọọtọ
ti wọn fi kan an, eyi to nii ṣe pẹlu iwa
ifipabanilopọ.
AWIKONKO gbọ pe ọdun 2010 ni
Newton-Wusu gbe awọn igbese yi, tọrọ naa si di
isu ata yanyan nigba naa, ṣugbọn ti wọn pada pana ẹ, ko too di ọdun to kọja ti wọn tun gbe ẹjọ naa dide.
Ohun ta a gbọ ni pe awọn ọmọ tọjọ ori wọn ko ju ọdun meẹẹdogun lọ lawọn ọmọ naa ti wọn sọ pe ọkunrin naa n
fipa ba laṣepọ, to si tun
n fun wọn ni kokeeni mu, lero wipe bi wọn ba n mu, aṣiri ko nii
tu.
Lọjọ Wẹside ọsẹ to kọja yi nigba
to n sọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan
oun, agbẹjọro ọkunrin naa,
Samuel Nwaji rawọ ẹbẹ sile ẹjọ pe ko faaye
silẹ lati gba beeli ẹ nitori pe ọsibitu lo wa
to ti n gba itọju latari aisan to daa dubulẹ.
Ṣaaju asiko
yi ni agbẹjọro ileewe
naa, Sọlomọn Maren sọ pe awọn ọmọ naa ni
Deborah Bala, ọmọdun mejila;
Susan Rayner, ọmọdun mẹrinla;
Eunice Bitrus, ọmọdun mẹrinla;
Rifkatu Musa, ọmọdun mẹẹdogun ati
Elizabeth Dogo ti Newton n fipa ba sun.
Onidajọ naa, Sọlomọn Olugbemi
ti wa a paṣẹ pe ki wọn ṣi gba beeli ọkunrin naa
nitori pe ẹsun ti wọn fi kan ko
ni ki wọn ma gba beeli ẹ, o si sun
igbẹjọmin in siwaju di asiko ti ara ẹ yoo fi ya.
No comments:
Post a Comment