AṢIRI ỌGA ILEEWE AWỌN ỌMỌ-ORUKAN TO N FIPA B’AWỌN OMODE SUN TU, O TI FOJU BALE ẸJỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 25, 2019

AṢIRI ỌGA ILEEWE AWỌN ỌMỌ-ORUKAN TO N FIPA B’AWỌN OMODE SUN TU, O TI FOJU BALE ẸJỌ

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
Ọga agba ileewe awọn ọmọ ọrukan to wa niluu Abeokuta, iyẹn Stephen Centre International, Rẹfurẹndi Isaac Oluwọle Newton-Wusu ti foju bale ẹjọ latari ẹsun marun ọtọọtọ ti wọn fi kan an, eyi to nii ṣe pẹlu iwa ifipabanilopọ.

AWIKONKO gbọ pe ọdun 2010 ni Newton-Wusu gbe awọn igbese yi, tọrọ naa si di isu ata yanyan nigba naa, ṣugbọn ti wọn pada pana ẹ, ko too di ọdun to kọja ti wọn tun gbe ẹjọ naa dide.

Ohun ta a gbọ ni pe awọn ọmọ tọjọ ori wọn ko ju ọdun meẹẹdogun lọ lawọn ọmọ naa ti wọn sọ pe ọkunrin naa n fipa ba laṣepọ, to si tun n fun wọn ni kokeeni mu, lero wipe bi wọn ba n mu, aṣiri ko nii tu.

Lọjọ Wẹside ọsẹ to kọja yi nigba to n sọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun, agbẹjọro ọkunrin naa, Samuel Nwaji rawọ ẹbẹ sile ẹjọ pe ko faaye silẹ lati gba beeli ẹ nitori pe ọsibitu lo wa to ti n gba itọju latari aisan to daa dubulẹ.

Ṣaaju asiko yi ni agbẹjọro ileewe naa, Sọlomọn Maren sọ pe awọn ọmọ naa ni Deborah Bala, ọmọdun mejila; Susan Rayner, ọmọdun mẹrinla; Eunice Bitrus, ọmọdun mẹrinla; Rifkatu Musa, ọmọdun mẹẹdogun ati Elizabeth Dogo ti Newton n fipa ba sun.

Onidajọ naa, Sọlomọn Olugbemi ti wa a paṣẹ pe ki wọn ṣi gba beeli ọkunrin naa nitori pe ẹsun ti wọn fi kan ko ni ki wọn ma gba beeli ẹ, o si sun igbẹjọmin in siwaju di asiko ti ara ẹ yoo fi ya.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI