Agbábọ́ọ̀lù
ọwọ́ iwájú ọmọ ilẹ̀ wa, Asisat Oshoala ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin
ti ikọ̀ Barcelona.
Asisat,
ẹni tó gúnlẹ̀ sínú ikọ̀ náà láti bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò àti ìtọwọ́bọ̀wé lánàá, Ọjọ́bọ̀,
ló kúrò nínú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù rẹ̀, Dalian Quanjian ti orilẹ̀ èdè China, láti
darapọ̀mọ́ Barca gẹ́gẹ́ bí agbábọ́ọ̀lù àyálò.
Gẹ́gẹ́
bí ìròyìn tí ikọ̀ Barca fi síta, agbábọ́ọ̀lù
náà yóò wà nínú ikọ̀ náà títí di ìparí sáà ìdíje 2018/19.
Nígbà
tó ń sọ̀rọ̀, Asisat fi ìdùnnú rẹ̀ sí ìtọwọ́bọ́wé náà jẹ́ pẹ̀lú àlàyé pé ohun
ìwúrí ni ó jẹ́ fún òun láti fi hàn fi ẹ̀bùn òun hàn nínú ikọ̀ tí ó gbajúmọ̀
lágbàáyé.
Ó ní
àfojúsùn òun ni láti fi ìtàn tuntun balẹ̀ nípa kíkó ipa ribibibi nínú ẹgbẹ́
agbábọ́ọ̀lù náà lójúnà àtiṣaseyege.
No comments:
Post a Comment