ẸGBẸ ONIROYIN YORUBA LORI AYELUJARA LALẸHU NI NAIJIRIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, February 27, 2019

ẸGBẸ ONIROYIN YORUBA LORI AYELUJARA LALẸHU NI NAIJIRIA

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Lati tubọ mu ilọsiwaju de ba ọkan lara awọn ede to gbajumọ julọ lagbaye, iyẹn ede Yoruba, ati paapaa nipa gbigbe Aṣa ati iṣẹṣe Yoruba larugẹ, awọn onkọroyin ede Yoruba lori ayelujara ti da ẹgbẹ tuntun silẹ.

Bẹ o ba gbagbe, awon onimọ iwoye agba kan ti so laipẹ yi pe bi yoo ba fi di odun 2023, ko nii si nnkan to n jẹ iroyin lede Yoruba mọ, nitori pe yoo ti parun, ki iwoye naa ma ba a si imuṣẹ lo bi ẹgbẹ LOYOPOM.

Ẹgbẹ naa ti wọn pe ni League of Yoruba Professional Online Media ni wọn ṣagbekalẹ ẹ lati tubọ mu irọrun de ba ede Yoruba.

Ninu ọrọ ọkan lara awọn oludasilẹ ẹgbẹ naa, Ọmọọba Aderounmu Kazeem lo ti sọ ọ di mimọ pe, “Ohun kan pataki to mu wa da ẹgbẹ yii silẹ ni bi ede abinibi wa; ti a fi n gbe iroyin sita ko ṣe ni i parun, ti igbelarugẹ nla yoo tubọ de ba a, ti awa ti a fi n gbe iroyin jade paapaa yoo ṣamulo ẹ lọna ti yoo fiwa han gẹgẹ bi ọmọluabi ti iran Yoruba n ṣe.”

Ọmọọba Aderounmu, ẹni to jẹ oludasilẹ, Magasinni Alore fi kun ọrọ ẹ pe, "Ọna kan pataki ti a tun le kọ awọn eeyan ni ede abinibi wa ni gbigbe iroyin sita pẹlu ede ọhun, eyi ti yoo fun wọn lanfaani lati maa pade awọn ẹwa ede loriṣiriṣi ninu iroyin ti wọn ba n ka, ti yoo si tun jẹ akagbadun fun wọn paapaa.

Lara awọn ileeṣẹ iroyin ti wọn wa lori ẹrọ ayelujara ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ yii ni, Iroyin Awikonko; Bo Ṣe Ri; Ojutole; Magasinni Alore; Magasinni Aṣejere at'awọn mi-in bakan naa.

Ẹgbẹ yii ti wa fidi ẹ mulẹ wi pe, gbogbo ilana to tọ, to si ba eto iroyin yii mu ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa n tẹle ninu ojuṣe wọn, ati pe ilọsiwaju iran Yoruba ati orile-ede yii lapapọ gan-an lo jẹ awọn logun nipa lilo ede Yoruba lati fi gbe ojulowo iroyin jade.

Ọmọọba Aderounmu wa a fi kun ọrọ ẹ pe anfaani wa fawọn min in to ba fẹ ẹ darapọ mọ ẹgbẹ naa, ati pe wọn gbọdọ ni ikanni nibi ti wọn ti royin pẹlu ede abinibi ti Yoruba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI