Ninu ọrọ to fi sọwọ sawọn
akọroyin ati loju opo Twitter rẹ, Atiku ni oun ko ni gba ki wọn fun okun mọ
ọrun ijọba awa ara wa lorileede Naijiria.
Atiku ni lati ọgbọn ọdun ti oun
ti n ja ija ijọba tiwantiwa, oun ko ti ri ibi ti wọn ti tẹju iṣejọba awa ara wa
loju mọlẹ bi ti idibo ọjọ kẹtalelogun osu Keji to waye ni Naijiria.
O sọ pe l'ọdun 2017 ''Aarẹ Yar
Adua ti ẹ kabamọ idibo to gbe wọlẹ, amọ o ṣeni laanu pe, awọn to doju ijọba
arawa bole lọdun 2019 n ga apa ni''
''Fun idi eyi, mọ tako esi ibo
ọjọ kẹtalelogun to waye ni Naijiria, maa si gbe ọrọ na lọ si ile ẹjọ''
Atiku Abubakar tẹsiwaju pe, oun
ko ba ti pe ẹni to jawe olubori lati ki ku oriire, kani oun fidirẹmi lọna to tọ
ati to yẹ.
PDP ní èsì ti wọn kéde kìí ṣe ojúlowo ìbò ti Nàìjíríà dì
Ẹgbẹ́ alátakò People's
Democratic Party (PDP) ní àwọn yóò ṣe gbogbo ǹkan to wà ní ìkápá àwọn, tó fi mọ
ìlànà òfin láti fi ẹ̀hónú àwọn hàn ló ri ìjáwé olúbori ààrẹ Muhammadu Buhari
nínú ìdìbò ọdún 2019.
Ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀hún tó kọ̀ láti
fọ́wọ́ sí ìwé èsì ìbò tí àjọ elétò ìdìbò fi kédé pé Buhari ló jáwé olúbori, tun
sọ pe o ní kọ́nukọ́họ ninu.
Lẹ́yìn ti INEC kédé pé, Buhari
ló fi ìdí Atiku rẹmi nínu idibo náà ní alága àjọ INEC ọjọgban Yakubu Mahmood
sàláyé pé ìyàtọ̀ tówà láàrin àwọn oludije méèjèjì pọ ju àwọn ìbò ti wọn dànù lọ
nítori náà kò ní ipa kànkan lóri èsì ìdìbò.
Media captionElection Update
2019: Lẹ́yìn lílọ Saraki, Kwara yóò ṣún síwájú ni
Gẹ́gẹ́ bí Yakubu ṣe sọ, gbogbo
àríwísí àti àkíyesi ti PDP ṣe ni àwọn yóò múlò ní ọjọ iwájú tó fi mọ ìdìbò ọdun
2023.
Lásikò tó ń fesi láàrò Ọ́jọrú,
lóri àbájáde ikede ìdìbo Buhari, okan ninu asojú ẹgbẹ PDP, Osita Chidoka sọ fun
àwọn akọroyin nílu Abuja pé, àwọn èsì ti wọn kéde kìí ṣe ojúlowo ìbò ti àwọn
ènìyàn Nàìjíríà dì.
- BBC
No comments:
Post a Comment