WAHALA NLA FẸẸ ṢẸLẸ NIPINLẸ OGUN LỌJỌ FRAIDE ỌSẸ YI, GOMINA AMOSUN LERI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 28, 2019

WAHALA NLA FẸẸ ṢẸLẸ NIPINLẸ OGUN LỌJỌ FRAIDE ỌSẸ YI, GOMINA AMOSUN LERI

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Titi dasiko ta a kọ iroyin yi tan, inu ibẹrubojo lawọn olugbe ipinlẹ Ogun wa bayii, pẹlu bi Gomina ipinlẹ naa, Ibikunle Amosun ṣe n fọwọ sọya leri lori afẹfẹ laarọ oni, Tọside pe abuku nla lawọn ti wọn lawọn fẹẹwa a fa wahala lọjọ Fraide ọla yi.

Laipẹ yi ni olori ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria labẹ Kọmureedi Ayuba Wabba gbe atẹjade sita pe awọn n bọ nipinlẹ naa lati wa a ti ipinlẹ naa pa pẹlu iwọde ifẹhonu han latari gbese, iyẹn owo oṣu ajẹẹlẹ ti Gomina jẹ awọn oṣiṣẹ.

Gomina Amosun nigba to n fesi si ọrọ naa nibi ifọrọwerọ ti ileeṣẹ redio Faaji lati ilu Eko wa a ṣe fun Gomina Amosun niluu Abẹokuta laarọ oni, o sọ pe wahala lawọn eeyan naa n fẹ da silẹ nitori pe ẹtẹ ni wọn maa ba pada bi wọn ba gbiyanju lati wa.


Gomina ninu ọrọ ẹ lo ti sọ pe "Ẹgbẹ awọn lawọn n bọ wa a ṣe iwọde, oṣelu ni wọn fẹ wa a ṣe o. Bi Ayuba Wabba ba de bi, abuku lo maa kan."

O ni kawọn to ba mọ olori awọn oṣiṣẹ pe, Ayuba Wabba tete sọ fun un pe to ba gbiyanju lati wa sipinlẹ Ogun gẹgẹ bi lẹta to fi ranṣe soun ṣe sọ pe ko ma gbiyanju ẹ wo, nitori pe ina iya toun ti da silẹ fun un ṣi n jo lọwọ.

Bẹẹ lo fi kun ọrọ ẹ pe oun ko jẹ oṣiṣẹ kankan lowo oṣu, to fi mọ ajẹẹlẹ ti wọn n pariwo.

Pupọ ninu awọn olugbe ipinlẹ naa, ti wọn nnkan ti Gomina Amosun sọ yi ni wọn ti wa ninu ibẹrubojo bayii nitori ti wọn mọ nnkan ti Gomina naa le ṣe, paapaa ti eyi ti wọn loo ṣe fun ẹgbẹ oṣelu APC nibi ipolongo ti wọn ṣe lọsẹ mẹta sẹyin ṣi n ja nilẹ titi dasiko yi.

Ohun tawọn eeyan n sọ ni pe ibi ti erin meji ba ti ja, afaimọ ki koriko to wa nitosi fara gba a.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI