EMI O KỌWE FIPO SILẸ O, DIGBI NI MO ṢI WA NINU OṢELU – OLU FALAE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 8, 2019

EMI O KỌWE FIPO SILẸ O, DIGBI NI MO ṢI WA NINU OṢELU – OLU FALAE

Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun 

Alaga ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, SDP lorileede Naijiria, Oloye Olu Falae ti pariwo sita pe oun ko kọwe fipo kankan silẹ, depodepo pe oun fi oṣelu silẹ patapata, o ni ahesọ lasan niroyin ti wọn gbe kaakiri.

Oloye Falae lo fidi ọrọ naa mulẹ fun akọroyin PUNCH lọsan onii niluu Akurẹ, o jẹ ko di mimọ pe lootọ loun fẹyin ti lati maa da si gbogbo oṣelu to n lọ lorileede yi, ṣugbọn ko kọwe fipo silẹ gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ oṣelu SDP.

Ninu ọrọ ẹ, o sọ pe “Mo kan pinu lati fẹyinti fun bi mo ṣe n da si ọrọ oṣelu lorileede yi nigba ti mo pe ọmọ ọgọrin (80) ọdun. Oṣu kẹsan an ọdun to kọja ni mo pe ọgọrin ọdun, mo fẹ ẹ kede ifẹyinti mi lọjọ naa, ṣugbọn ipade gbogboogbo ẹgbẹ ti sunmọ etile, lẹyin igba naa ni Ọjọgbọn Jerry Gana gbe wa lọ si kọọtu, idi ni yi ti mi o fi kede.

“Fun idi eyi, pẹlu ilana ẹgbẹ, Ọjọgbọ Tunde Adeniran ni alaga fidihẹ lapapọ bayii, mo ti fẹyinti, ṣugbọn mi o kọwe fipo naa silẹ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI