A KO ṢETAN LATI TI ỌNA PA L'EKO - IJỌBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 8, 2019

A KO ṢETAN LATI TI ỌNA PA L'EKO - IJỌBA

Aworan Komisana eto irina leko nibi ti wọn ti n ba akoroyin sọrọ
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe awọn ko ni ti ọna kankan pa lasiko abẹwo Aarẹ Muhammadu Buhari si ipinlẹ naa.

Ikede yii jẹ iyipada ikede ti wọn ti saaju fi sita pe awọn oju ọna kan yoo wa ni titi pa nigba ti Aarẹ Buhari ba wa fun ipolongo idibo ni papa iṣere agbegbe Surulere lọjọ ti.

Komisana fun irina nipinlẹ Eko Ladi Lawanson ṣalaye loju opo Twitter ijọba Eko pe iyipada yi waye lẹyin ti awọn ṣe agbeyẹwo eto irina ti wọn ti ṣe tele ti wọn si tẹti si ohun ti ara ilu sọ.

Inu fo aya fo lawọn ara ilu Eko kan wa lati igba ti ijọba kede titi awọn oju ọna kna pa nitori abẹwo Aarẹ Buhari sipinlẹ naa.

Lọpọ igba ti awọn alaṣẹ pataki bi Aarẹ ba ṣe abẹwo si ipinlẹ Eko ni inira ma a n ba ara ilu nipasẹ sunkere fakere ọkọ ti o ma n tele iru abẹwo bẹẹ.

Bi a ko ba gbagbe, ijọba ipinlẹ Eko ya ọjọ ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, Osù Kẹẹ̀ta ọdun to kọja gẹ́gẹ́bí ọjọ́ Ìsinmi fún àwọn òsísẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà lasiko ti Aarẹ Buhari ṣe abẹwo sipinlẹ naa lati ṣe ifilọlẹawọn akanṣe iṣẹ kan.

Toun ti ikede yii, awọn to jade lawọn agbegbe kan ke irora latari sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ to waye.

- BBC
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI