Bẹẹ naa ni awọn janduku to ṣe
ikọlu si ilu Dan Jibga nijọba ibilẹ Tsafe ni Zamfara ri iku he, nigba ti awọn
ara ilu naa pa mọkandinlọgọta lara wọn.
Iroyin fi han pe, ni bii agogo
kan oru ni awọn darandaran ṣe ikọlu naa ni abule Agatu, ti wọn n pe ni Ebete ni
Ipinlẹ Benue.
Bi wọn ṣe n yinbọn pà awọn
eniyan, ni wọn dana sun ile wọn.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni
ipinlẹ naa, Catherin Anene sọ fun awọn akọroyin wipe, iwadii n lọ lọwọ lori
ikọlu naa.
Ni Zamfara, a gbọ pe awọn
janduku bi ọgọsan lo ya bo ilu Dan Jibga, ti wọn si pa eniyan meje.
Ni kia ni a gbọ pe, awọn ara
ilu naa mu awọn mọkandinlọgọta lara awọn janduku naa, ti wọn si pa wọn.
Ija naa lọ fun bii wakati
mẹrin, ki awọn agbofinro to de ilu naa.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọmọogun
Naijirai, Clement Abiade ni awọn ti n gbiyanju lati ṣe iwadii lori bi ọrọ naa
ṣe ṣẹlẹ.
- BBC
No comments:
Post a Comment