IKUNLẸ ABIYAMỌ O: EYI NI BI TIRELA MẸTA ṢE TẸ AKẸKỌỌ MEJI ATI EEYAN MẸFA PA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 21, 2019

IKUNLẸ ABIYAMỌ O: EYI NI BI TIRELA MẸTA ṢE TẸ AKẸKỌỌ MEJI ATI EEYAN MẸFA PA

Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun

Ọjọ buruku eṣu gbomimu laarọ oni Tọside jẹ niluu Nnewi nipinlẹ Anambra nigba ti wọn sọ pe tirela mẹta ọtọọtọ kọlu ara wọn, nibi tawọn eeyan mẹfa ti dagbere faye, tọpọ awọn eeyan si farapa jati-jati.

AWIKONKO gbọ pe awọn akẹkọọ meji tile-ẹkọ girama Nneoma to wa lagbegbe Otolo Nnewi la gbọ pe wọn ba iṣẹlẹ buruku naa lọ lasiko ti wọn n lọ sileewe wọn, ikorita Akwudo niluu Nnewi niṣẹlẹ naa ti waye.
Ohun ta  a gbọ ni pe, tirela kan to n ko igbẹ lo lọọ fori sọ tirela nla kan toun ko epo, toun naa si lọọ fori sọ tirela ileeṣẹ ọlọti, iyẹn Nigerian Brewery, eyi ti wọn paaki sẹgbẹ titi nibẹ.

Awakọ tirela to wa eyi to ko epo, Ugochukwu ati obinrin ti wọn jọ wa ninu tirela naa pẹlu awọn to kagbako iku ojiji, ati pe awọn akẹkọọ meji naa, asiko ti wọn sọda sodikeji ileewe wọn nijamba naa lọ ba wọn.

Bi iṣẹlẹ buruku naa ṣe ṣẹlẹ, wọn lawọn gendekunrin to wa lagbegbe naa lasiko naa sare lọọ dana sun awọn tirẹla naa, ti wọn tun ji ọpọlọpọ ọti ti ko din ni ọgọrun kan katọọnu ko salọ.


Awọn ọlọpaa agbegbe naa la gbọ pe wọn pada gbe awọn oku naa lọ si mọṣuari ti ọsibitu kan ti wọn pe ni Akwudo.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI