GBOGBO NNKAN TO YẸ NI MO NI LATI DI GOMINA IPINLẸ OGUN LODUN 2019 YI - IYADUNNI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, February 3, 2019

GBOGBO NNKAN TO YẸ NI MO NI LATI DI GOMINA IPINLẸ OGUN LODUN 2019 YI - IYADUNNI

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
Adije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu United Democratic Party, UDP, Oloye (Arabinrin) Jackie Adunni Kassim ti f'ọwọ ẹ sọya pe gbogbo awọn nnkan to yẹ patapata loun ni lati di gomina ipinlẹ Ogun ninu idibo gomina to n bọ lọjọ keji oṣu kẹta ọdun yi.

Jackie Adunni Kassim lo sọrọ lọjọ Abamẹta to kọja yi ninu atẹjade ti ẹni to jẹ alakoso feto iroyin ati bo ṣe n lọ ẹ, Ọgbẹni Fẹmi Oyewẹsọ fi ranṣẹ si AWIKONKO.

O ni ko si nnkan ti wọn n beere fun lati di olori, paapaa gomina nipinlẹ Ogun toun ko ni lọwọ, ati pe pẹlu b'oun tun ṣe sunmọ araalu to, o f'ọkan oun balẹ pe ipo naa yoo ja moun lọwọ.

Adunni Kassim tawọn tun n pe ni Iyadunni tun ni bi wọn ba n so nipa oṣelu alailẹtan, oṣelu ti kii ṣoju ṣaaju, oun mo nipa ẹ daadaa nitori pe gẹgẹ bi abiyamọ to bimọ rẹpẹtẹ, onitọhun gbọdọ nifẹ awọn ọmọ ẹ bakan naa.

O tẹnu mọ ọn pe bi ifẹ awọn eeyan ṣe jẹ oun logun to, lo jẹ k'awọn alatilẹyin oun ni koun jade lati dupo naa, ti ogunlọgọ awọn araalu jakejado si f'ọwọ sii.

Bẹẹ lo sọ pe pẹlu ọgbọn, imọ, oye, ọlaju ati b'oun ṣe mo awọn eeyan jankan-jankan to lorileede Naijiria ati lagbaye, loun yoo lo lati rii pe idagbasoke de ba ipinlẹ Ogun lọna ti ko ṣẹlẹ ri.

Iyadunni wa a ni k'awọn eeyan ma wo o pe tori oun jẹ obinrin, ki wọn fi oju tẹmbẹlu oun nitori pe obinrin gan an lo mọ bi iya ṣe n jẹ awọn eeyan, to si ṣetan lati gbọ bukaata wọn.

O wa a rọ awọn oludibo pe ki wọn jade sita rẹpẹtẹ lati dibo foun, ati pe ki wọn dan obinrin wo lasiko ko, toun si fi dawọn loju pe oun yoo so eso rere fun ipinlẹ Ogun.

Lakotan, Iyadunni rawọ ẹbẹ si ajọ eleto idibo, INEC pe ki wọn ma ṣe ojusaaju ninu eto idibo naa, ki wọn si kede ẹni to ba wọle gẹgẹ bo ti tọ ati bo ti yẹ, ki alaafia le tubọ maa jọba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI