OWÓ LÀWỌN ỌMỌ NÀÍJÍRÍÀ YÓÒ MÁA FI GBA KÁÀDÌ ÌDÁNIMỌ̀ WỌN BẸ̀RẸ̀ LÁTI ỌDÚN 2022 – NIMC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 2, 2019

OWÓ LÀWỌN ỌMỌ NÀÍJÍRÍÀ YÓÒ MÁA FI GBA KÁÀDÌ ÌDÁNIMỌ̀ WỌN BẸ̀RẸ̀ LÁTI ỌDÚN 2022 – NIMC


Àjọ tó ń ṣe ìforúkọsílẹ̀ àti pínpín káàdì ìdánimọ̀ nílẹ̀ wa, NIMC ti sọ́ ọ di mímọ̀ pé láti ọdún 2022 ló ni àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí máa gba owó lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàíríjíà fún ìforúkọsílẹ̀ àti gbígba káàdì ìdánimọ wọn.

Ọ̀gá àgbà fún àjọ̀ náà, Aliyu Aziz ló sípayá ọ̀rọ̀ yìí níbi iwẹ̀jéwẹ̀mu tí àjọ tó ń rí sí àtúntò ìṣẹ́ ìjọba, Bureau of Public Services Reforms (BPRS) sé lọ́jọ́ Ẹtì láti bá àjọ náà jíròrò lóri ṣíṣe ìforúkọsílẹ̀ àwọn ọmọ Nàíjíríà lọ́nà ti ìgbàlódé.

Aziz, ẹni tó gba àwọn ọmọ Nàíjíríà níyànjú láti tètè ṣe ìforúkọsílẹ̀ wọn láàárin àsìkò yìí sí ìgbà náà, sọ wí pé ìforúkọsílẹ̀ náà yóò bá tolówó dé èyí tí wọn kò tí i fi síta.

Ó ní káàdì igbàlódé náà ló wà fún àwọn ọmọ Nàíjíríà tí ọjọ́ orí bẹ̀rẹ̀ láti ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún lọ sókè tí ó sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn níbi tí wọ́n ti ṣe àkójọpọ̀ orúkọ àwọn ọmọ ilẹ̀ wọn síbi tó pa mọ́.

Ó ṣàlàyé pé àjọ náà mọ pàtàkì lílo ìmọ̀ ẹ̀rọ dígítà fún ṣíṣe àkójọpọ̀ àti ìtọ́jú orúkọ àwọn ará ìlú lọ́nà àtimú ìdàgbàsókè bá awùjọ nítorí náà ni wọ́n yóò ṣe gùnlé lílo ìmọ̀ dígítà láti ṣe ìforúkọsílẹ̀ àwọn ọmọ Nàíjíríà.

Aziz, nígbà tó ń tẹ̀síwájú pé ìgbésẹ̀ akin ni ìjọba fi ìforúkọsílẹ̀ onídígítà ṣe, gba àwọn ará ìlú lámọ̀ràn láti fi gbígbọ́ ṣe aláìgbọ́ lórí ọ̀rọ̀ pé àwọn ènìyàn ti wọn kò ní nọ́ǹbà ìdánimọ̀ (NIN) ni wọn kò ní ní àǹfání láti lo àwọn iléeṣẹ́ ìjọba kankan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI