GOMINA AMOSUN FAWỌN OLORI L’ẸKA IṢẸ IJỌBA IBILẸ TẸLẸ LOWO IFẸYINTI WỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, February 13, 2019

GOMINA AMOSUN FAWỌN OLORI L’ẸKA IṢẸ IJỌBA IBILẸ TẸLẸ LOWO IFẸYINTI WỌN


Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta 

Pẹlu idunnu ati ayọ lawọn ti wọn ti di ipo oṣelu mu lẹka ijọba ibilẹ kaakiri ipinlẹ Ogun fi gba owo to tọ si wọn gẹgẹ bi owo ifẹyinti lonii ọjọ Wẹside, ni gbagede tawọn ologun to wa ni Oke-Mọsan niluu Abẹokuta.

Awọn ti wọn ti dipo oṣelu ijọba ibilẹ mu laarin ọdun 2007 si ọdun 2010 la gbọ pe wọn gba owo naa, wọn to fi mẹfa din ni l’Ẹgbẹrin (793) lawọn ti wọn jẹ anfaani owo yi, lẹsẹkẹsẹ ni Gomina Amosun ti fun wọn niwe sowe-dowo wọn.

AWIKONKO gbọ pe biliọnu meji aabọ (2.5b) naira lowo tawọn eeyan naa gba, bẹẹ la si gbọ pe awọn ti wọn dipo oṣelu nijọba ipinlẹ laarin ọdun 2007 si ọdun 2015 naa gba ninu owo yi pẹluu

A gbọ pe ọdun 2014 ni Gomina Amosun bẹrẹ eto naa, nigba to fawọn to wa nipele akọkọ lowo, to si tun tẹsiwaju pẹlu ipeleke keji lọdun 2016, ko too di onii to fawọn to wa nipele kẹta lowo ti wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI