Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta
Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ lọsan oni ba fi le jẹ otitọ, a jẹ pe ija ṣẹṣẹ tun
bẹrẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun ni, latari bi wọn ṣe sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ
oṣelu APC to wa lẹyin Dapọ Abiodun pẹlu atilẹyin Oloye Ṣẹgun Ọṣọba fẹẹ ṣiṣẹ fun
adije sipo Sẹnetọ labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, Ọnarebu Titilayọ Oseni-Gomez
AWIKONKO gbọ pe awọn agbaagba
kan ninu ẹgbẹ naa oṣelu APC ni wọn ṣepade ikọkọ lana Tuside latari ọna ti wọn
fẹẹ gba lati fiya jẹ Gomina Ibikunle Amosun tou n du ipo Sẹnetọ.
Gẹgẹ bi ọkan pataki ninu ẹgbẹ
oṣelu naa to loun wa nibi ipade naa ṣe sọ fun AWIKONKO, ẹni to ni ka forukọ
boun laṣiri ṣe sọ, o ni ọna ti yoo ya Gomina Amosun lẹnu lawọn fẹẹ gba lati
fiya jẹ ẹ.
‘Kaka k’eku ma jẹ sese, a maa
fi ṣe awadanu ni’ lẹni naa sọ fun wa, pẹlu bo ṣe sọ pe wọn ti pinu pe bi Gomina
Amosun ba ṣi n kọ lati ṣagbatẹru Ọmọba Dapọ Abiọdun, Titi Oseni ti ẹgbẹ oṣelu
ADC ni wọn fẹẹ dibo fun gẹgẹ bii Sẹnetọ.
Bẹ o ba gbagbe, ipolongo idibo
iapdabọ Aarẹ Buhari lẹẹkeji to waye lọjọ Mọnde ijẹta niluu Abẹokuta, nibi ti
wọn ti dana iya fawọn ọmọ ẹyin Dapọ Abiọdun atawọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu naa, to
fi mọ Aarẹ Buhari ati Adams Ọṣhiọmọlẹ funra ẹ, la gbọ pe o bi awọn Ọṣọba ninu,
ti wọn fi |sepade naa.
A si gbọ pe awọn ọmọ ẹyin Oloye
Ṣẹgun Ọṣọba ti n sọ fun ara wọn pe wọn ko gbọdọ dibo fun Gomina Amosun gẹgẹ bi
Sẹnetọ to fẹẹ ṣoju Aarin Gbungbun ipinlẹ Ogun, iyẹn Ogun Central.
Wọn ni bi Amosun ba kọ lati
tẹle Dapọ Abiọdun, awọn naa ko nii dibo fun gẹgẹ bii Sẹnetọ, kaka bẹẹ, kawọn
kuku ran Titi Oseni lọwọ lati de ipo naa, ati pe ‘gba fun muri, ni gba fun
gbada’.
No comments:
Post a Comment