ÌBÒ 2019: ÌJỌ GOFAMINT GBỌ́HÙN ÀDÚRÀ SÓKÈ FÚN ÀLÁFÌÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 4, 2019

ÌBÒ 2019: ÌJỌ GOFAMINT GBỌ́HÙN ÀDÚRÀ SÓKÈ FÚN ÀLÁFÌÀ


Ìjọ Glory Centre Assembly tí i ṣe ẹ̀ka ìjọ Gospel Faith Mission International (GOFAMINT) kan ní ìlú Ìbàdàn lọ́jọ́ Àìkú, tẹ̀síwájú nínú àdúrà wọn láti bẹ̀bẹ̀ fún àláfìà nínú ètò ìdìbò tí yóò wáyé láìpẹ́.

Orísìírísìí àkànṣe àdúra láti bẹ̀bẹ̀ fún àláfìà pàápàá lórí àwọn onírúurú rógbòdìyàn àti fàákája tó ń wáyé lágbo òṣèlú ni àwọn ọmọ ìjọ náà fohùn wọn gbé sókè sỌ́lórun.

Gẹ́gẹ́ bí Bámidélé Morádékẹ̀ Aya Olúnúsì ṣe sọ, “orísìírísìí àwọn ìfihàn àtí ìsípayá tó ń farahàn nípa àwọn olọ́ṣèlú tó ń díje nínú ìdìbò tó ń bọ̀ ló ń  ba lẹ́rù ni gan-an. Níbi tí àwọn kan ti gbà pé àfẹ́fẹ́ àláfíà ni yóò jọba nínú ìdìbò náà ni àwọn kan tí wọ́n gbàgbọ́ pé ìtàjẹ̀sílẹ̀ lọ̀rọ̀ ìdìbò náà gbà. Ṣùgbọ́n ní tiwa, àdúrà láìsìmi àti láìṣàárẹ̀ ni àwa yóò máa ṣe”.

Ó tẹ̀síwájú pé, “Kí a mú ọkàn wa kúrò lọ́dọ̀ àwọn olóṣèlú ẹlẹ́tàn kí a sì fi ìgbàgbọ́ sínu Ọlọ́run olùgbàlà wa. Kí a bẹ́ Ọlọ́run láti yan ẹni tó wù Ú lọ́kàn fún wa nítorí ìgbẹ́kẹ̀lé wa kò sí nínú ènìyàn bí kòse nínú Ọlọ́run láti fún wa lẹ́ni tó tọ́”.

Ó tọ́ka rẹ̀ pé púpọ̀ nínú àwọn tó ń lépa wàhálà náà ló ní ibi tí wọ́n ń forí pa mọ́ sí tí wọ́n sì ń dá ọ́ràn ọ̀ún sọ́rùn àwọn àráàlú tí wọn ò mọwọ́mẹṣẹ̀.

Aya olúnúsì náà ṣàlàyé pé Ọlọ́run nìkan ló lè gbà àwọn ọmọ Nàíjíríà lọ́wọ́ isòro tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn olùdarí burúkú dá sí wọn lọ́rùn pẹ̀lú àdúrà pé ìmọ̀ àwọn ẹni ibi lórí Nàíjíríà kò ní jọ.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Alàgbà Olúṣẹ́gun Ọmọ́tọ̀sọ́ pe àwọn ọmọ ìjọ náà níjà láti jígìrì sí ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bíi ọmọ Nàíjíríà rere kí wọ́n sì yàgò fún ẹ̀tàn àwọn olóṣèlú.

Ó fi kún un pé kí wọ́n fi ìbò wọn lé Ọlọ́run lọ́wọ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run yóò yan ẹni bíi tirẹ̀ sórí oyè.

Lára àwọn tó tukọ̀ ètò àdúrà náà ni Olùṣọ́àgùntàn ìjọ náà; Olùṣọ́àgùntàn Solomon Babaṣọlá, Olùṣọ́àgùntàn Mesack Ọlọ́rundá, Olùṣọ́àgùntàn Gbéńga Ọ̀túnla, Díákónì obìnrin Olúbùnmi Fáladé àti Alàgbà Olúṣẹ́gun Ọmọ́tọ̀sọ́.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI