INÚ MI DÙN PÉ KÒ SÍ OHUN TÓ ṢE Ọ̀SÍNBÀJÒ – ATIKU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 4, 2019

INÚ MI DÙN PÉ KÒ SÍ OHUN TÓ ṢE Ọ̀SÍNBÀJÒ – ATIKU


Adíje sípò àarẹ ilẹ̀ wa kan lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democractic Party (PDP), Atiku Abubakar ti fi ìdùnnú rẹ̀ hàn lórí bí Ọlọ́run ṣe kó Ìgbákejì Àaré ilẹ̀ wa, Ọjọ̀gbọ́n Yẹmí Ọ̀sínbàjò yọ nínú ijàmba ọkọ́ òfurufú hẹlikọ́pítà tó sẹlẹ̀ lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Ọjọ́ Àbámẹ́ta tí ìsẹ̀lẹ̀ náà sẹlẹ̀ ni ìròyìn ti kan Atiku lára tí ó sì gba ìkannì ayélujára rẹ̀ lórí Twitter lọ lọ́jọ́ Àìkú láti kí Ìgbákejì Àaré náà kú ẹwu.

Ó ní òun bá Ọ̀sínbàjò yọ̀ pé àláfíà ara ni òun àti àwọn ikọ̀ tí wọ́n tẹ̀le e wà.
Bákan náà ni ìròyìn tọ́ ń tẹ Awíkonko lọ́wọ́ ṣàlàyé pé tìdùnnú-tìdùnnú ni Ọ̀jọ́gbọ́n Yẹmí Ọ̀sínbàjò fi lọ sílé ìjọsìn lọ́jọ́ Àìkú láti fọpẹ́ fỌ́lọ́run fún dídá ẹ̀mí rẹ̀ sí.

Ìdúpẹ́ pàtàkì náà ló wáyé ní ilé ìjọsìn Redeemed Christian Church of God (RCCG), City of Grace tó wà ní Lokoja níbi tí Olùsọ́àgùntàn Àgbà fún ilé ìjọsìn náà, Olùsọ́àgùntàn Enoch Adébóyè ti bá Ìgbákejì Àarẹ wa fi àdúrà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run àbò naà.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI