IBO AARẸ: BA A ṢE YỌ JONATHAN LA ṢE MAA YỌ BUHARI - ATIKU LERI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 21, 2019

IBO AARẸ: BA A ṢE YỌ JONATHAN LA ṢE MAA YỌ BUHARI - ATIKU LERI

Adije sipo Aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Atiku Abubakar, ba awọn alatilẹyin rẹ sọrọ lori ẹrọ ayelujara ti Twitter ati Facebook lonii Ọjọbọ, nibi to ti rọ wọn pe ki wọn jade lọ dibo lọjọ Abamẹta to n bọ yi.

Atiku ni, ori oun wu nigba ti awọn ọmọ Naijiria fi kaadi idibo wọn yọ Aarẹ ana, Goodluck Ebele Jonathan lasiko idibo to waye ni ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 2015.

O ni, "Awa eniyan Naijiria lọ si ibi idibo pẹlu kaadi idibo wa nikan, a si yọ olori orilẹede yii nigba naa. Oun to jẹ ki ori mi wu niyẹn gẹgẹbii ọmọ Naijiria. Ni ọsẹ yii, a o ni anfani lati ṣe bẹẹ lẹẹkan si."

Atiku tẹsiwaju, o ni eni yoowu ti awọn ọmọ Naijiria ba fẹ dibo fun, ki wọn gbiyanju lati jade dibo lọjọ Abamẹta.

O ni ni ọjọ idibo, ibo kan ko lagbara ju omiran lọ.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI